Posts

*MINING # ÌWAKÙSÀ*

Image
*MINING # ÌWAKÙSÀ* Oríkì: Ìwakùsà ni akitiyan yíyọ àwọn ohun oníyebíye jáde kúrò nínú ilẹ̀. Agbooléeṣẹ́ ìwakùsà ní Nàìjíríà níkòósínú onírúurú ọrọ̀ àlùmọ́nì tó lè fàyè gba ìdàgbà agbooléeṣẹ́ ní 10% nínú ìdàgbàsókè gbogboogbò ní ti ọrọ̀ajé. Nàìjíríà ní ìbùnkún àwọn ọrọ̀ àlùmọ́nì oníyeorí léyìí tó ń dásí àgbéjáde abẹ́lé kíkún lọ́wọ́lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tó ju 90%. Àwọn àlùmọ́nì gbòógì tó wà ní Nàìjíríà ni epo-rọ̀bì, èédú, kùsà irin, tínìn àti kòlóńbáìtì, okúta ẹfun, òjé àti sínǹkì. YouTube embedding powered by embed.tube * Components of Nigerian mining industry # Àwọn ẹ̀yà agbooléeṣẹ́ ìwakùsà ní Nàìjíríà* (1)   Petroleum # Epo-rọ̀bì: Epo-rọ̀bì ni àlùmọ́nì àpáta gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí à ń rí ní Pọtá ní Ìpínlẹ̀ Rivers, Warri àti Úgéli ní Ìpínlẹ̀ Delta, Ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom àti ti Ìmò. A gbẹ́ kànǹga epo àkọ́kọ́ ní Nàìjírí...

*AGRICULTURE # IṢẸ́-Ọ̀GBÌN*

Image
  *AGRICULTURE # IṢẸ́-Ọ̀GBÌN* Oríkì: Iṣẹ́-ọ̀gbìn ni a lè kì kedere gẹ́gẹ́ bíi ìgbéjáde àwọn irè-oko àti ọ̀sìn àwọn ẹranko fún lílò ènìyàn. Ní gbólóhùn mìíràn, iṣẹ́-ọ̀gbìn ni ìgbìyànjù àmọ̀ọ́nmọ̀ṣe láti ọwọ́ ènìyàn láti túlẹ̀, láti dáko àti láti sin àwọn ẹranko fún oúnjẹ àti fuǹ àwọn èrèdí mìíràn.            Iṣẹ́-ọ̀gbìn jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn abala pàtàkì jùlọ nínú ọrọ̀ajé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn orílẹ̀èdè Ìwọ̀oòrùn Áfíríkà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń mú iṣẹ́-ọ̀gbìn ṣe jáléjáko ní àkàsọ̀ àrojẹ, bíi 60 sí 70 ìdá nínú ọgọ́ọ̀rún iye ènìyàn Ìwọ̀oòrùn Áfíríkà ló gbà síṣẹ́. YouTube embedding powered by embed.tube * Components of agriculture # Àwọn ẹ̀yà iṣẹ́-ọ̀gbìn* Iṣẹ́-ọ̀gbìn ní àwọn ẹ̀yà tàbí àwọn ẹ̀ka púpọ̀. Àwọn ẹ̀yà rẹ̀ pàtàkì jùlọ ni: (1)   Crop production # Ìgbéjáde irè-oko: Èyí ni ẹ̀ka iṣẹ́ ọ̀gbìn tó...