*AGRICULTURE # IṢẸ́-Ọ̀GBÌN*
*AGRICULTURE # IṢẸ́-Ọ̀GBÌN*
Oríkì:
Iṣẹ́-ọ̀gbìn ni a lè kì kedere gẹ́gẹ́ bíi ìgbéjáde àwọn irè-oko àti ọ̀sìn
àwọn ẹranko fún lílò ènìyàn. Ní gbólóhùn mìíràn, iṣẹ́-ọ̀gbìn ni
ìgbìyànjù àmọ̀ọ́nmọ̀ṣe láti ọwọ́ ènìyàn láti túlẹ̀, láti dáko àti
láti sin àwọn ẹranko fún oúnjẹ àti fuǹ àwọn èrèdí mìíràn.
Iṣẹ́-ọ̀gbìn jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn
abala pàtàkì jùlọ nínú ọrọ̀ajé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn orílẹ̀èdè Ìwọ̀oòrùn
Áfíríkà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń mú iṣẹ́-ọ̀gbìn ṣe jáléjáko ní àkàsọ̀
àrojẹ, bíi 60 sí 70 ìdá nínú ọgọ́ọ̀rún iye ènìyàn Ìwọ̀oòrùn
Áfíríkà ló gbà síṣẹ́.
*Components of agriculture # Àwọn ẹ̀yà iṣẹ́-ọ̀gbìn*
Iṣẹ́-ọ̀gbìn
ní àwọn ẹ̀yà tàbí àwọn ẹ̀ka púpọ̀. Àwọn ẹ̀yà rẹ̀ pàtàkì jùlọ ni:
(1) Crop
production # Ìgbéjáde irè-oko: Èyí ni
ẹ̀ka iṣẹ́ ọ̀gbìn tó ní nǹkan í ṣe gbòógì pẹ̀lú dídá oko. Ìgbéjáde
irè-oko ni a pín sí ìsọ̀rí méjì gbòógì: àwọn irè-oko jíjẹ àti àwọn
ire-oko àsọdowó. À ń dáko irè-oko jíjẹ láti pèsè oúnjẹ fún àwọn
olùgbélùú tàbí gbòógì fún ìṣàmúlò. Àpẹẹrẹ irè-oko jíjẹ ni ìrẹsì,
agbado, ẹ̀pà, ewébẹ̀, iṣu, ẹ̀gẹ́, abbl. Àwọn ire-oko àsọdowo nídàkejì ni
à ń dáko rẹ̀ gbòógì fún títà. Ní gbólóhùn mìíran, àwọn irè-oko
àsọdowó ni à ń gbéjáde nípìlẹ̀ fún ìkójáde láti pawó wọlé tàbí
fún pàṣípààrọ̀ òkèèrè fún ọrọ̀ajé orílẹ̀èdè àti fún ìlò àwọn
iléeṣẹ́. Àpẹẹrẹ irè-oko àsọdowó ni kòkó, ọsàn, rọ́bà, òwú àti ọ̀pẹ.
(2) Livestock
farming # Ọ̀sìn ẹran: Ọ̀sìn ẹran
níkòósínú sínsin àwọn ẹranko yálà fún ìṣàmúlò tàbí fún títà.
Àwọn ẹran ọ̀sìn ni mààlúù, àgùntàn, ewúrẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, adìẹ,
ehoro, ìgbín àti ọ̀yà. A máa ń sin àwọn ẹran ọ̀sìn yìí fún àwọn
èrèdí púpọ̀, fún àpẹẹrẹ, fún ẹran, àsọdowó, ìrìnkèrindò àti
eré-ìdárayá.
(3) Forestry #
Ìtọ́jú igbó: Ìtọ́jú igbó ni iṣẹ́ gbíngbin, ìtọ́jú
àti ìdarí àwọn igbó, tó fi mọ́ ìṣàmúlò àwọn àgbéjáde rẹ̀. Púpọ̀
jùlọ nínú àwọn igi tí à ń rí nínú igbó ni ó jẹ́ èyí tó ń hù
jáde fúnra rẹ̀ tàbí tí à ń gbìn fún àwọn èrèdí pàtó. Apákan
lára àwọn igi tí a sábà máa ń rí nínu igbo ni Ìrókò, Òbéṣè,
Màhógánì, Ẹ́bónì, Òpèpé, Afàrà àti Tíìkì. Igbó ṣe pàtàkì
fún ìpèsè oúnnẹ, epo, egbògi, iṣẹ́, ẹran-igbó, pàṣípààrọ̀
òkèèrè, gẹdú àti ẹ̀bẹ̀tẹ̀ fún pépà ṣíṣe.
(4) Fish
farming # Ọ̀sìn ẹja: Ọ̀sìn ẹja ni iṣẹ́
sínsin àwọn àṣàyàn ẹ̀yà ẹja lábẹ́ àwọn ìṣesí tí a kójàánu pẹ̀lú
sáyẹ́ńsì nínú àwọn àkámọ́ ibú omi bíi àwọn adágún, akérémọdò,
odò, àgbáńlákun, abbl, níbi tí wọ́n ti ń jẹun, dàgbà, bísíi tí a
sì ń kórè wọn fún ìṣàmúlò tàbí fún títà. Ọ̀sìn ẹja máa ń pèsè oúnjẹ, iṣẹ́, owó-àpawọlé
àti pàṣípààrọ̀ òkèèrè fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ orílẹ̀èdè, pàápàá tí a
bá kó àwọn ẹja náà jáde lọ sí àwọn orílẹ̀èdè mìíràn.
*Systems of agriculture # Àwọn ètò iṣẹ́ ọ̀gbìn*
1)
Peasant farming # Iṣẹ́ oko àrojẹ: Iṣẹ́ oko
àrojẹ ni a lè kì gẹ́gẹ́ bí irú iṣẹ́ ọ̀gbìn tí ó ní nǹkan í ṣe pẹ̀kú
ìgbéjáde oúnjẹ fún àgbẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Ní gbólóhùn mìíràn, ó
jẹ́ ètò iṣẹ́ oko kan níbi tí àgbẹ̀ kan ti ń dáko àwọn irè oko tó sì
ń sin àwọn ẹran ọ̀sìn lójúnà àti-pèsè oúnjẹ fún lílò ara rẹ̀ àti
ìdílé rẹ̀ nìkan.
*Characteristics of peasant farming # Àwọn àbùdá iṣẹ́ oko àrojẹ*
(a) Ó nílò agbègbè ilẹ̀ kékeré.
(b) Làálàá ìdílé ni a sábà máa ń lò.
(c) Ìkórè tí a máa ń rí nínú irú oko bẹ́ẹ̀ sábà
máa ń kéré.
(d) Àwọn irinṣẹ́ rọ̀bì bíi àdá, ọkọ́, abbl. ni a sábà
máa ń lò.
(e) Kì í sábà ṣẹ́kù ju díẹ̀ bó bá tiẹ̀ ṣẹ́kù rárá
fún títà.
(f) Ó nílò ojúowó kekèré láti múṣiṣẹ́.
(g) Irè oko jíjẹ bíi ìrẹsì, iṣu àti àgbàdo ni a
sábà máa ń gbìn.
2)
Plantation farming # Iṣẹ́ oko aládàáńlá: Iṣẹ́ oko aládàáńlá níkòósínú dídáko àwọn irè oko ọlọ́rọ̀ajé
kan sórí agbègbè ilẹ̀ fífẹ̀. Nínú irú iṣẹ́ oko yìí irè oko kan ṣoṣo
ni a máa ń gbìn sórí agbègbè ilẹ̀ fífẹ̀ kan.
*Characteristics of plantation farming # Àwọn àbùdá iṣẹ́ oko aládàáńlá*
(a) Ó nílò agbègbè ilẹ̀ fífẹ̀.
(b) Ó nílò ìdókòwò ojúowó gọbọi.
(c) Irè oko kan ṣoṣo ni a máa ń gbìn.
(d) Ó nílò lílò àwọn ẹ̀rọ bíi katakata, irin-ìtúlẹ̀,
abbl.
(e) Ìkórè máa ń pọ̀ yan̄turu.
(f) A lè ní in láti ọwọ́ ìjọba, àwọn aládàáni tàbí àwọn
àjọ.
(g) Àtìjáde tàbí ìkórè máa ń wà gbòógì fún
títà.
3)
Mechanised farming # Iṣẹ́ oko àfẹ̀rọṣe: Iṣẹ́ oko àfẹ̀rọṣe, tí a tún mọ̀ sí iṣẹ́-ọ̀gbìn káràkátà, jẹ́ irú
iṣẹ́-ọ̀gbìn tó ní nǹkan í ṣe pẹ̀lú ìgbéjáde oúnjẹ, àwọn ẹran àti
àwọn irè-oko àsọdowó ní ṣeéwọ̀n yan̄turu gbòógì fún títà. Ẹ̀yà iṣẹ́
oko àfẹ̀rọṣe kan ni iṣẹ́ oko ìpínlẹ̀. Iṣẹ́ oko ìpínlẹ̀ ni ètò iṣẹ́-ọ̀gbìn
kan nínú èyí tí ìpínlẹ̀, nípasẹ̀ àwọn àjọ-aṣojú rẹ̀, máa ń kópa
nínú iṣẹ́ oko aládàáńlá fún ọjà abẹ́lé àti ti òkèrèrè pẹ̀lú.
*Characteristics of mechanised farming # Àwọn àbùdá iṣẹ́ oko àfẹ̀rọṣe*
(a) Ó nílò agbègbè ilẹ̀ fífẹ̀.
(b) Àwọn àmúṣagbára tó dájú tó sì jẹ́ tòde-òní
bíi àwọn katakata, fíkofíko àti túlẹ̀túlẹ̀ ni a máa ń lò.
(c) Ó nílò ìdókòwò ojúowó gọbọi.
(d) Ó nílò àwọn ìgbáradì ìwátajà alákànṣe.
(e) A sábà máa ń kójàánu àwọn jokojoko àti àwọn
àrùn.
(f) Ó nílò àwọn àkọ́mọ̀ àkànṣe àti ìkọ́lẹ́kọ̀ọ́ ní
ti ìmọ̀-ètò tàbí làálàá.
(g) Ìgbéjáde wà gbòógì fún títà.
(h) A nílò ìfipamọ́ àti àwọn ìrọ̀rùn ìṣàtúndá.
(i) A máa ń mú un ṣe púpọ̀ jùlọ láti ọwọ́ àwọn àgbẹ̀
olówó gidi, àwọn kọ́ńpìnnì àti àwọn ìjọba.
4)
Co-operative farming # Iṣẹ́ oko aláfọwọ́sowọ́pọ̀: Èyí ni irú iṣẹ́ oko nínú èyí tí àwọn àgbẹ̀ ti n kórajọ láti dá
ẹgbẹ́ kan sílẹ̀ fún èrèdí ìṣiṣẹ́ oko papọ̀ láti lè mú kí wọ́n lè jẹ̀gbádùn
àwọn móríwú kan lọ́dọ̀ ìjọba. Irúfẹ́ àwọn móríwú bẹ́ẹ̀ lè
níkòósínú àwọn ẹ̀yáwó, ìpèsè àtìwọlé bíi àwọn ajílẹ̀, àwọn
ìrànwọ́ àti ìmúkúrò ìrọ̀rùn àwọn àgbéjáde wọn nípasẹ̀ ìwátajà
elétò.
*Characteristics of co-operative farming # Àwọn àbùdá iṣẹ́ oko aláfọwọ́sowọ́pọ̀*
(a) Ó jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀.
(b) Wọ́n lè ṣe igbéjáde irú irè oko tàbí ẹran-ọ̀sìn
kan.
(c) Wọ́n máa ń jẹ̀gbádùn àwọn móríwú kan lọ́dọ̀ ìjọba,
fún àpẹẹrẹ, ilẹ̀ àti àwọn àtiwọle ẹlẹ́dìnínwó.
(d) Ó ní àwọn ọjà elétò fún àwọn àgbéjáde wọn.
(e) Àtijáde máa ń ga nítorí àwọn ọrọ̀ ti àwọn àgbẹ̀
tùjọ.
*Importance or contribution of agriculture to
economic development of West Africa # Pàtàkì tàbí ìdásí iṣẹ́-ọ̀gbìn sí ìdàgbàsókè ọlọ́rọ̀ajé ti
Ìwọ̀oòrùn Àfíríkà*
(1) Provision
of food # Ìpèsè oúnjẹ́: Iṣẹ́-ọ̀gbìn
máa ń pèsè oúnjẹ bíi agbado, ìrẹsì, ẹran, wàrà àti ẹyin fún ìṣàmúlò
ọmọnìyàn, yálà ní tútù tàbí ní ìrí àtúndá.
(2) Provision
of materials for clothing # Ìpèsè àwọn
ohun-èlò fún aṣọ: Iṣẹ́-ọ̀gbìn máa ń pèsè owú àti fọ́nránwùú fún
ìgbéjáde aṣọ, bàtà, ìgbànú, fìlà àti àpò.
(3) Employment for the working population # Ìpèsè iṣẹ́
fún àwọn agbélùú tó ń ṣiṣẹ́: Iṣẹ́-ọ̀gbìn àti àwọn agbooléèṣẹ ajẹmọ́ṣẹ́-ọ̀gbìn
máa ń pèsè àwọn àǹfààní iṣẹ́ fún 60 sí 70% àwọn agbélùú.
(4) Source of
foreign exchange # Orísun pàṣípààrọ̀
òkèèrè: Nípasẹ̀ ìkójáde àwọn àgbéjáde iṣẹ́-ọ̀gbìn bíi kòkó,
obì, ẹ̀pà, èròjà ọ̀pẹ àti òwú, orílẹ̀èdè kan máa ń lágbára láti
pawó lórí pàṣípààrọ̀ òkèèrè.
(5) Generation
of income # Ìgbéjáde owó àpawọlé:
Títà àwọn irè oko àti àwọn àgbéjáde wọn, àwọn ẹran-ọ̀sìn àti àwọn àgbéjáde
wọn, máa ń pèsè owó-àpawọlé fún àwọn àgbẹ̀.
(6) Provision
of materials for shelter # Ìpèsè àwọn
ohun-èlò fún ilégbèé: Iṣẹ́-ọ̀gbìn máa ń pèsè àwọn ohn-èlò
pàtàkì fún ìkọ́lé, bíi àwọn òpó, ìlẹ̀kùn, fèrèsé, òrùlé àti
àwọn ohun-èlò tí a nílò fún àwọn amúléyẹ bíi àwọn àga, tábìlì
àti ìbùsùn.
(7) Development
of towns # Ìdàgbàsokè àwọn ìlú:
Ìdàgbàsókè máa ń ṣẹlẹ̀ níbi ti iṣẹ́-ọ̀gbìn káràkátà wà, ní bí
àwọn ohun amúlùúdùn bíi ẹ̀lẹ́tíríkì, omi inú ọ̀pá àti àwọn òpópọ́nà
yóò ṣe di pípèsè.
(8) Provision
of facilities for recreation and tourism # Ìpèsè àwọn ìrọ̀rùn fún ìdárayá àti ìgbafẹ́: Iṣẹ́-ọ̀gbìn máa
ń yọrí sí ìgbékalẹ̀ àwọn ibi ìyàsọ́tọ̀ àwọn ẹranko àti ìpèsè àwọn
ẹṣin fún ìdíje ẹlẹ́ṣin àti bọ́ọ̀lù ẹlẹ́ṣin pẹ̀lú.
(9) Provision
of market for industrial goods # Ìpèsè ọjà
fún àwọn ire agbooléeṣẹ́: Iṣẹ́-ọ̀gbìn
máa ń pèsè ọjà fún àwọn agbéjáde agbooléeṣẹ́ bíi àwọn ẹ̀rọ ìdáko,
kẹ́míkà, ajílẹ̀, ìṣàtúndá àti ìrọ̀rùn ìkópamọ́.
(10)
Provision of raw materials for industries # Ìpèsè àwọn ohun èlò atokodé fún àwọn agbooléeṣẹ́:
Iṣẹ́-ọ̀gbìn máa ń pèsè àwọn ohun èlò atokodé fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn
agbooléeṣẹ́ fún bíbẹ títí. Àwọn agbooléeṣẹ́ tó gbaralé iṣẹ́-ọ̀gbìn
fún àwọn ohun èlò atokodé wọn ni à ń pè ní agboléeṣẹ́ ajẹmọ́ṣẹ́-ọ̀gbìn.
Fún àpẹẹrẹ, agbooléeṣẹ́ ohun mímu gbaralé kòkó fún ìgbéjáde ọ̀pọ̀lọ́pọ̀
oúnjẹ àpòmu bíi Bournvita, Pronto àti Ovaltine. Bákan náà
ni àwọn agbooléeṣẹ́ ìrànwú, ìhunṣọ àti àwọn agbooléeṣẹ́ aṣọ híhun
mìíràn máa ń gbáralé irun ẹranko àti owú tààrà fún ìgbéjáde àwọn
ohun èlò aṣọ.
*Contribution of agriculture to industrial
development of Nigeria # Ìdásí iṣẹ́-ọ̀gbìn
sí ìdàgbàsókè agbooléeṣẹ́ ti Nàìjíríà*
(1) Provision
of food # Ìpèsè oúnjẹ: Iṣẹ́-ọ̀gbìn
máa ń pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà, àlékún nínú wíwà
oúnjẹ sì túmọ̀ sí àlákún nínú ìgbáyégbádùn àwọn ọmọnílùú.
(2) Provision
of raw materials # Ìpèsè àwọn ohun èlò
atokodé: Abala agbooléeṣẹ́ gbáralé iṣẹ́-ọ̀gbìn fún àwọn ohun-èlò
atokodé rẹ̀, fún àpẹẹrẹ, ìrèké, kòkó, èròjà ọ̀pẹ àti òwú.
(3) Revenue
for farmers and government # Owó-àpawọléeṣẹ́
fún àwọn àgbẹ̀ àti ìjọba: Iṣẹ́-ọ̀gbìn máa ń pèsè owo-àpawọléeṣẹ́
fún àwọn àgbẹ̀ àti ìjọba Nàìjíríà.
(4) Provision
of employment # Ìpèsè iṣẹ́: Iṣẹ́-ọ̀gbìn
máa ń pèsè iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọmọ Nàìjíríà tí ì bá jẹ́ aláìníṣẹ́.
(5) Provision
of foreign exchange # Ìpèsè pàṣípààrọ̀
òkèèrè: Èròjà iṣẹ́-ọ̀gbìn, fún àpẹẹrẹ, òwú, rọ́bà àti kòkó,
máa ń jèrè pàṣípààrọ̀ òkèèrè fún orílẹ̀èdè.
(6) Provision
of market for industrial goods # Ìpèsè ọjà
fún àwọn ire agbooléeṣẹ́: Iṣẹ́-ọ̀gbìn máa ń pèsè ọjà fún àtijáde
tàbí awọn ire agbooléeṣẹ́ ní bí àwọn àgbẹ yóò ṣe máa ra àwọn ire
agbooleeeṣẹ́ bíi ọkọ́, àdá, katakata àti àwọn ajílẹ̀ fún lílò.
~Hakeem
O. Adeniyan, 23/3/2022
+2347034251583

Comments
Post a Comment