COMMERCIAL BANKS # BÁŃKÌ KÁRÀKÁTÀ
YouTube embedding powered by embed.tube *COMMERCIAL BANKS # BÁŃKÌ KÁRÀKÁTÀ* Oríkì : Báńkì káràkátà jẹ́ ìgbékalẹ̀ olówónàá kan tó máa ń gba ìjùúlẹ̀ àti àwọn ohun iyebíye mìíràn láti ọ̀dọ̀ aráàlú fún ìfipamọ́ aláìléwu, pẹ̀lú àfojúsùn kan ṣoṣo láti jèrè. Ní gbólóhùn mìíràn, báńkì káràkátà jẹ́ ìgbékalẹ̀ olówónàá kan tó máa ń ṣe iṣẹ́-ìsìn ìmúdání owó àti àsùnwọ̀n àwọn ènìyàn àti lílò irúfẹ́ owó bẹ́ẹ̀ láti pèsè ẹ̀yáwó àti àwọn iṣẹ́-ìsìn olówónàá fún àwọn oníbàárà. Àwọn ẹ̀yáwó náà máa ń sábà wà fún àsìkò kúkúrú àti àsìkò ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àwọn ẹni kọ̀ọ̀kan aládàáni, àwọn ìgbékalẹ̀ tàbí àwọn ìjọba ló máa ń ni báńkì káràkátà. Ó jẹ́ kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke. Díẹ̀ nínú àwọn báńkì káràkátà ní Nàìjíríà ni: First Bank of Nig. Plc., Union Bank of Nig. Plc., Zenith Bank Plc., Access Bank Plc., Diamond Bank P...