*MINING # ÌWAKÙSÀ*
*MINING # ÌWAKÙSÀ* Oríkì: Ìwakùsà ni akitiyan yíyọ àwọn ohun oníyebíye jáde kúrò nínú ilẹ̀. Agbooléeṣẹ́ ìwakùsà ní Nàìjíríà níkòósínú onírúurú ọrọ̀ àlùmọ́nì tó lè fàyè gba ìdàgbà agbooléeṣẹ́ ní 10% nínú ìdàgbàsókè gbogboogbò ní ti ọrọ̀ajé. Nàìjíríà ní ìbùnkún àwọn ọrọ̀ àlùmọ́nì oníyeorí léyìí tó ń dásí àgbéjáde abẹ́lé kíkún lọ́wọ́lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tó ju 90%. Àwọn àlùmọ́nì gbòógì tó wà ní Nàìjíríà ni epo-rọ̀bì, èédú, kùsà irin, tínìn àti kòlóńbáìtì, okúta ẹfun, òjé àti sínǹkì. YouTube embedding powered by embed.tube * Components of Nigerian mining industry # Àwọn ẹ̀yà agbooléeṣẹ́ ìwakùsà ní Nàìjíríà* (1) Petroleum # Epo-rọ̀bì: Epo-rọ̀bì ni àlùmọ́nì àpáta gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí à ń rí ní Pọtá ní Ìpínlẹ̀ Rivers, Warri àti Úgéli ní Ìpínlẹ̀ Delta, Ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom àti ti Ìmò. A gbẹ́ kànǹga epo àkọ́kọ́ ní Nàìjírí...