*MINING # ÌWAKÙSÀ*
*MINING # ÌWAKÙSÀ*
Oríkì: Ìwakùsà ni akitiyan yíyọ àwọn ohun oníyebíye
jáde kúrò nínú ilẹ̀. Agbooléeṣẹ́ ìwakùsà ní Nàìjíríà
níkòósínú onírúurú ọrọ̀ àlùmọ́nì tó lè fàyè gba ìdàgbà
agbooléeṣẹ́ ní 10% nínú ìdàgbàsókè gbogboogbò ní ti ọrọ̀ajé.
Nàìjíríà ní ìbùnkún àwọn ọrọ̀ àlùmọ́nì oníyeorí léyìí tó ń
dásí àgbéjáde abẹ́lé kíkún lọ́wọ́lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tó ju 90%. Àwọn
àlùmọ́nì gbòógì tó wà ní Nàìjíríà ni epo-rọ̀bì, èédú, kùsà
irin, tínìn àti kòlóńbáìtì, okúta ẹfun, òjé àti sínǹkì.
*Components of Nigerian mining industry # Àwọn ẹ̀yà agbooléeṣẹ́ ìwakùsà ní Nàìjíríà*
(1) Petroleum # Epo-rọ̀bì: Epo-rọ̀bì ni àlùmọ́nì àpáta gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí à ń rí ní Pọtá ní
Ìpínlẹ̀ Rivers, Warri àti Úgéli
ní Ìpínlẹ̀ Delta, Ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom àti ti Ìmò.
A gbẹ́
kànǹga epo àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà ní Oloibiri lẹ́bàá Pọtá. Àwọn
Kànǹga epo mìíràn la rí ní Afam, Ugeli, Warri, Egbema, abbl.
Ohun tó bá
epo-rọ̀bì kẹ́gbẹ́ pẹ́kípẹ́kí ni afẹ́fẹ́ àdámọ́ tí à ń lò fún
ìdáná. A máa ń fọ epo-rọ̀bì nípasẹ̀ ìlànà kan tí à ń pè ní ríro
ọlọ́tọ̀ọ̀tọ̀ (fractional distillation) ní
àwọn ibùdó-ìfọpo tó wà ní Pọtá, Warri, àti Kàdúná láti pèsè àwọn
àgbéjáde bíi pẹtiró, kẹ́rosín, dísù àti gírísì.
*Method of mining petroleum # Ìlànà wíwa epo-rọ̀bì*
Ọ̀nà
tí à ń gbà wa epo-rọ̀bì ni ọ̀nà ìdálẹ̀lu. Nínú ọ̀nà yìí, a máa ń
ṣe ìyànlápẹẹrẹ àti àyẹ̀wò àwọn àpáta abẹ́le fún àwọn àmì bíbẹ
epo. Nígbà tí a bá ṣàwárí epo náà, a óò gbẹ́ kànǹga kan láti dé
ibẹ̀ pẹ̀lú ìrànwọ́ ẹ̀rọ ìdálẹlu. A óò wá fún epo náà jáde ní ti
àfẹ̀rọṣe tàbí ní ti àdámọ́ bí títẹ̀ láàárín agbègbè epo náà
nínú ilẹ̀ bá ga.
Nínú ilẹ̀, àwọn ipele mẹ́ta ló
wà láàárín agbègbè epo.
(a) A máa ń ri afẹ́fẹ́ àdámọ́ lókè.
(b) A máa ń rí epo-rọ̀bì láàárín.
(c) A máa ń rí omi nísàlẹ̀.
(2) Coal # Èédú: Èyí jẹ́
orísun mìíràn fún agbára. Èédu, bíi ti epo-rọ̀bì, jẹ́ àlùmọ́nì
àpáta gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí a máa ń rí ní Enugu àti Okaba ní Ìpínlẹ̀
Benue. Irú èédú tó wà ní Nàìjíríà ni ẹtún ipele oníbítumẹ́ẹ̀nì.
A sábà máa ń lo èédú ní gbòógì gẹ́gẹ́ bí orísun ìkòná nínú
ilé àti nínú ẹ́ǹjìn reluwé látijọ́.
*Method of mining coal # Ìlànà wíwa èédú*
(a) A óò gbẹ́ isà wọnú àpáta èédú náà.
(b) A óò lo àwọn abúgbàmù láti wú àwọn èédú náà
jáde.
(c) A óò lo ọkọ̀ reluwé kékeré kan láti kó èédú
náà láti inú isà náà wá sí ojúde tàbí sínú àwọn ọkọ-àjàgbé
láti inú ibi tí a óò ti kó o jáde lọ sí àwọn orílẹ̀èdè mìíràn
tàbí kí á lò ó lábẹ́lé.
(3) Iron ore #
Kùsà irin: Kùsà irin jẹ́ àlùmọ́nì àpata dídíjú ìpìlẹ̀
tí a rí ní Ìtàkpé ní Ìpínlẹ̀ Kogí àti Aladja ní Ìpínlẹ̀ Delta.
Kùsà irin ni a máa ń kó wọnú ilé-àhunpọ̀ irin àti irínle ní Ajaokuta
Ìpínlẹ̀ Kogi àti Aladja nítòsí Warri ní Ìpínlẹ̀ Delta.
Àwọn ilé-ẹ̀rọ fún ìrọ irin àti irínle wà ní Òṣogbo Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun,
Jos Ìpínlẹ̀ Plateau àti Katsina Ìpínlẹ̀ Katsina.
*Method of
mining iron ore # Ìlànà
wíwa kùsà irin*
A máa
ń wa kùsà irin nípasẹ̀ ìlànà kan tí à ń pè ní ìjáálẹ̀ ṣíṣí.
Ìrìnàjò náà lọ báyìí:
(a) A óò lo àwọn abúgbàmù láti mú àpáta ẹrù-orí
kúrò.
(b) A óò wá lo ẹ̀rọ alágbára kan tí à ń pè ní gbẹ́hògbẹ́hò
láti kó kùsà irin náà jọ̀ bí òkè.
(c) A óò wá lo ọ̀pátu (nozzle) kan láti darí
ìtu omi alágbára kan sí ara òkè náà.
(d) Omi náà yóò fọ yẹ̀pẹ̀ jáde nípasẹ̀ ọ̀wọ́ àwọn asẹ́
kan.
(e) Kùsà irin náà yóò já sí ìsàlẹ̀ àwọn asẹ́ náà
nígbà tí omi yóò gbé àwọn ìdọ̀tí lọ.
(f) Irin àmúki tí a ṣẹ̀dá yìí ni a óò padà fí ṣọwọ́
sí ilé-ìgbéjáde fún yíyọ́.
(4) Tin and
columbite # Tínìn àti kòlóńbáìtì:
Tínìn àti kòlóńbáìtì jẹ́ àlùmọ́nì àpáta dídíjú ìpìlẹ̀ tí a
rí nítòsí Jos Ìpínlẹ̀ Plateau. À ń lo tínìn fún ìkunjú àwọn agbè
ní agbooléeṣẹ́ ìfagolotọ́jú nígbà tí à ń lo kòlóńbáìtì nínú ìṣàgbélẹ̀rọ
irínle alátakò ooru tí à ń lò nínú ẹ́ńjìn. Tínìn àti
kòlóńbáìtì máa ń wà papọ̀ ní ti àdámọ́.
*Method of
mining tin and columbite # Ìlànà
wíwa kùsà tínìn àti kòlóńbáìtì*
A máa
ń wa kùsà tínìn nípasẹ̀ ìlànà kan tí à ń pè ní ìjáálẹ̀ ṣíṣí.
Ìrìnàjò náà lọ báyìí:
(a) A óò lo àwọn abúgbàmù láti mú àpáta ẹrù-orí
kúrò.
(b) A óò wá lo ẹ̀rọ alágbára kan tí à ń pè ní gbẹ́hògbẹ́hò
láti kó kùsà tínìn náà jọ̀ bí òkè.
(c) A óò wá lo ọ̀pátu (nozzle) kan láti darí
ìtu omi alágbára kan sí ara òkè náà.
(d) Omi náà yóò fọ yẹ̀pẹ̀ jáde nípasẹ̀ ọ̀wọ́ àwọn asẹ́
kan.
(e) Kùsà tínìn náà yóò já sí ìsàlẹ̀ àwọn asẹ́
náà nígbà tí omi yóò gbé àwọn ìdọ̀tí lọ.
(f) Tínìn àmúki tí a ṣẹ̀dá yìí ni a óò padà fí ṣọwọ́
sí ilé-ìgbéjáde fún yíyọ́.
(5) Limestone
# Òkúta ẹfun: Òkúta ẹfun jẹ́ àlùmọ́nì àpáta gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí a
rí ní Ewékorò àti Ṣàgámù Ìpínlẹ̀ Ògùn, Ukpilla Ìpínlẹ̀ Edo, Calabar Ìpínlẹ̀ Cross River, Nkalagu Ìpínlẹ̀ Anambra, Ìpínlẹ̀ Benue àti Ìpínlẹ̀ Sókótó.
Òkúta-ẹfun jẹ́ ohunèlò atokodé tó ṣe kókó fún ìṣàgbélẹ̀rọ sìmẹ́ńtì.
A ní láti ṣàkíyèsí wí pé a fi àwọn agbooléeṣẹ́ sìmẹ́ńtì sọlẹ̀ sí
gbogbo àwọn agbègbè òkè yìí níbi tí a ti rí òkúta ẹfun.
*Method of mining limestone # Ìlànà wíwa okúta ẹfun*
A máa
ń wa òkúta ẹfun nípasẹ̀ ìlànà kan tí à ń pè ní ìwàkúta.
Ìrìnàjò náà lọ báyìí:
(a) A óò ha àwọn àpáta ẹrù-òkè kúrò pẹ̀lú ẹ̀rọ gbẹ́hògbẹ́hò
láti lè dé ibi òkúta ẹfun náà.
(b) A óò wá fọ́ òkúta ẹfun náà pẹ̀lú àwọn
abúgbàmù tí a óò sì kó o jáde nípasẹ̀ àwọn gbẹ́hògbẹ́hò náà
sínú àwọn ọkọ̀ àjàgbé tó ń dúró láti gbé e lọ sí ibi-ìgbéjáde.
(6) Lead and
zinc # Òjé àti sínǹkì: Òjé àti sínǹkì jẹ́ àlùmọ́nì àpáta gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀
tí a rí ní Abakaliki ní Ìpínlẹ̀ Ebonyi. A máa ń lò wọ́n gbòógì ní
àwọn agbooléeṣẹ́ lábẹ́lé.
*Adverse effects of mining in the area of
operation # Àwọn ìlapa búburú
ìwakùsà ní agbègbè ìmúṣiṣẹ́*
(1) Ìsọdàìmọ́ àyíká
(2) Ìmóoru àgbáyé nípasẹ̀ ìgbéjáde àwọn afẹ́fẹ́
(3) Ìbàjẹ́ àyíká
(4) Ìdàgbàsókè àwọn ìlú ahoro
(5) Ìparun ètò-ìṣepọ̀
(6) Ìmúkúrò àwọn ìletò
(7) Ìpàdánù àwọn ilẹ̀ oko àti ilẹ̀ ìkẹ́ranjẹko
(8) Ìjà ìlúsílùú
(9) Ìdínkù ipá làálàá ní ti iṣẹ́-ọ̀gbìn
(10)
Àwọn ewu
ìlera, fún àpẹẹrẹ, ikọ́ sémìínsémìín, àìdúróore ẹ̀dọ̀fóró àti ọkàn
(11)
Àwọn ewu
ìwakùsà, fún àpẹẹrẹ, ìwólulẹ̀ ibi ìwakùsà
*Importance of minerals to the Nigerian economy
# Ìṣepàtàkì àwọn àlùmọ́nì
sí ọrọ̀ajé Nàìjíríà*
(1) Employment
# Ìpèsè iṣẹ́: Wíwa àwọn àlùmọ́nì wọ̀nyìí máa ń pèsè iṣẹ́
fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn.
(2) Revenue
generation # Ìgbéjáde owó-àpawọléeṣẹ́: Àwọn owó-orí tí àwọn kọ́ńpìnnì ìwakùsà san,
tó fi mọ́ àwọn ojúṣe ìkójáde àti ìkówọlé lórí àwọn àlùmọ́nì, jẹ́
orísun owó-àpawọléeṣẹ́ fún ìjọba.
(3) Foreign
exchange earning # Ìpawó
lórí pàṣípààrọ̀ òkèèrè:
Ìkójáde àwọn àlùmọ́nì bíi epo-rọ̀bì, èédú àti tínìn, máa ń
pèsè pàṣípààrọ̀ òkèèrè fún orílẹ̀èdè.
(4) Provision
of essential goods # Ìpèsè àwọn
ire tó ṣe kókó: A máa ń fa àwọn ire
àti àwọn àgbéjáde tó ṣe kókó yọ lára àwọn àlùmọ́nì, fún àpẹẹrẹ,
epo-rọ̀bì máa ń pèsè kẹrosín, pẹtiró, gírísì, òróró ẹ́ńjìn àti
ìkòná ọkọ̀-òfúrufú.
(5) Raw
materials for industries # Àwọn
ohun-èlò atokodé fún àwọn agbooléeṣẹ́: Àwọn ohun-èlò atokodé bí òkúta-ẹfun ni àwọn agbooléeṣẹ́ sìmẹ́ńtì
máa ń lò; agbooléeṣẹ́ irin àti irínle máa ń lo kùsà irin.
(6) Improvement
of standard of living # Ìmúdárasíi
ìgbéayé ìpéwọ̀n: Owó tí a
pa lórí àwọn àlùmọ́nì ni a máa ń lò láti pèsè àwọn ohun
amúlùúdùn tó ṣe kókó láti mú ìgbéayé ìpéwọ̀n àwọn ènìyàn
dára síi.
(7) Acquisition
of skills # Ìjèrè àwọn àkọ́mọ̀: Wíwá àti wíwà àwọn àlùmọ́nì wọ̀nyìí máa ń jẹ́
kí àwọn ènìyàn jèrè oríṣìíríṣìí àkọ́mọ̀.
(8) Infrastructural
development # Ìdàgbàsókè
àpótí-ajé: Wíwa àwọn àlùmọ́nì
ní agbègbè kan máa ń yọrí sí ìdàgbàsókè àwọn àpótí-ajé bíi
pópónà, ẹ̀lẹ́tíríkì, ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ àti omi inú ọ̀pá ní agbègbè
bẹ́ẹ̀.
(9) Growth of
cities # Ìdàgbà àwọn ìlú-ńlá: Àwọn ìlú-ńlá bíi Enugu, Jos àti Warri dàgbà
látàrí wíwa èédú, tínìn àti epo-rọ̀bì létòlétò.
(10)
Production of geological maps # Ìgbéjáde àwọn máàpù onímọ̀ìjìnlẹ̀-ilẹ̀: Ìwákiri àwọn àlùmọ́nì ní orílẹ̀èdè yìí ti yọrí
sí ìgbéjáde àwọn máàpù onímọ̀ìjìnlẹ̀-ilẹ̀ kan.
(11)
Transfer of technology # Ìtàtaré ìṣàmúlò-ẹ̀rọ: Wíwá tàbí wíwà àwọn àlùmọ́nì ní orílẹ̀èdè yìí sábà máà
ń yọrí sí ìtàtaré ìṣàmúlò-ẹ̀rọ láti àwọn orílẹ̀èdè alágbooléeṣẹ́.
(12)
Training and retraining of personnel # Ìkọ́mọ̀ọ́nṣe àti ìtúnkọ́mọ̀ọ́nṣe àwọn òṣìṣẹ́: Àwọn akitiyan ìwakùsà ní Nàìjíríà ti yọrí sí
ìkọ́mọ̀ọ́nṣe àti ìtúnkọ́mọ̀ọ́nṣe àwọn òṣìṣẹ́ lójúnà kí wọ́n lè
jáfáfá nínú àwọn ìmúṣiṣẹ́ ìwakùsà.
(13)
Growth of ancillary industries # Ìdàgbà àwọn agbooléeṣẹ́ alátẹ̀lé: Wíwa àwọn àlùmọ́nì tàbí àwọn akitiyan ìwakùsà
máa ń yọrí lákòópọ̀ sí ìgbékalẹ̀ àwọn agbooléeṣẹ́ alátẹ̀lé tó lè
ṣe ìgbélárugẹ àwọn akitiyan ìwakùsà ní orílẹ̀èdè yìí.
(14)
Income to miners # Owó-apáwọlé fún àwọn awakùsà: Àwọn ènìyàn tó jẹ́ awakùsà ti lo ọ̀nà yìí
láti pawó wọlé fúnra wọn.
(15)
Provision of essential goods # Ìpèsè àwọn ire tó ṣe kókó: Àwọn ire tó ṣe kókó bíi sìmẹ́ńtì, wúrà, rọ́bà
oníke àti táyà ni a sábà máa ń gbéjáde nípasẹ̀ àwọn akitiyan
ìwakùsà.
(16)
Improvement of balance of payments # Ìmúdárasíi ìbádọ́gba ìsanwó: Ìkójáde àwọn àlùmọ́nì lọ sí àwọn orílẹ̀èdè
òkèèrè ti ṣèrànwọ́ láti fa ìmúdárasíi bá ìbádọ́gba ìsanwo
láàárín orílẹ̀èdè méjèèjì tó ń kópa nínú iṣòwò àgbáyé.
*Problems facing mining of minerals in Nigeria
# Àwọn ìṣòro tó ń kojú
wíwa àwọn àlùmọ́nì ní Nàìjíríà*
(1) Inadequate
capital # Àìtó ojúowó: Owónàá kì í sábà tó fún ìwákiri tàbí wíwa
àwọn àlùmọ́nì ní orílẹ̀èdè yìí.
(2) Poor
transportation network # Àhunpọ̀
ìgbérìnkèrindò tó mẹ́hẹ: Púpọ̀ jùlọ
nínú àwọn ibi tí àwọn àlùmọ́nì sọlẹ̀ sí ni kò ṣe í dé pẹ̀lú ọ̀nà
tó dára àti ètò reluwé.
(3) Use of
outdated topographical maps # Lílo
àwọn máàpù alápèjúweebi ìkàsè: Púpọ̀ jùlọ nínú àwọn máàpù tí à ń lò fún ìwákiri àwọn
àlùmọ́nì ní orílẹ̀èdè yìí ti dìkàsè.
(4) Inadequate
personnel # Àìtó àwọn òṣìṣẹ́: Àwọn òṣìṣẹ́ onímọ̀-ètò tí a nílò láti wá àwọn
àlùmọ́nì kiri ni a kò kọ́mọ̀ọ́nṣe tí wọn kò sì tó rárá.
(5) Difficult
terrain # Ojúulẹ̀ tó ṣòro: Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn awakùsà máa ń ní ìbápàdé
ojúulẹ̀ tó ṣòro lásìkò ìwákiri àwọn àlùmọ́nì tí èyí sì ń ṣàlékún
ìnáwó ìmúṣiṣẹ́ wọn lẹ́yìnọ̀rẹyìn.
(6) Fluctuations
in world prices # Ségesège iye-owóọjà
lágbàáyé: Ségesège wà nínú
iye-owóọjà púpọ̀ julọ nínú àwọn àlùmọ́nì lágbàáyé tí èyí sì ń
fa ìrẹ̀wẹ̀sì bá ìwákiri.
(7) Constant
conflicts # Ìjà ní gbogbo ìgbà: Ìṣòro ìjà ní gbogbo ìgbà máa ń wà láàárín
àwọn ọmọnílùú àti àwọn kọ́ńpìnnì tó ń wa àlùmọ́nì kiri.
(8) Environmental
pollution # Ìsọdàìmọ́ àyíká: Ìsọdàìmọ́ àyíká rẹpẹtẹ máa ń wà ní ti ilẹ̀,
ní ti atẹ́gùn, ní ti omi, bẹ́ẹ̀ náà ni ìdànù epo ní àwọn agbègbè tí
ìwakùsà ti ń wáyé.
(9) High level
of sabotage # Àkàsọ̀ gíga ní ti ìwà
mọ̀dàrú: Ìṣòro wà ní ti ìdíwọ̀n
gíga ìwà mọ̀dàrú láti ọwọ́ àwọn ènìyàn aláìnífẹ́ẹ̀lú ní àwọn
agbègbè ìwakùsà.
(10)
Poor management # Ìdarí tó mẹ́hẹ: Ìdarí tó
mẹ́hẹ ní ìbárìn pẹ̀lú ìwákiri ati wíwa àwọn àlùmọ́nì tó mẹ́hẹ ní
Nàìjíríà.
~Hakeem O. Adeniyan, 30/3/2022
+2347034251583

Comments
Post a Comment