MIGRATION # ÌṢÍKÚRÒ

*MIGRATION # ÌṢÍKÚRÒ*

Oríkì: Ìṣíkúrò ni a máa ń kì gẹ́gẹ́ bíi ìṣípòpadà àwọn ènìyàn kúrò  ní agbègbè onímọ̀-ilẹ̀ kan sí òmíràn, pẹ̀lú ìkópa ibùgbé tàbí ibùtẹ̀dó onígbà-pípẹ́ tàbí onígbà-díẹ̀. Ní ti ìṣíkúrò, agbègbè ibi tí àwọn ènìyàn ti ń kúrò ni à ń pè ní agbègbè orísun nígbà tí à ń pe agbègbè tí àwọn ènìyàn ń wọ̀ ní agbègbèe gbígbà tàbí agbègbè òpin-àjò.

*Types of migration # Oríṣiríṣi iṣíkúrò*

(1)  Emigration # Ìṣílọ: Èyí ni oríṣi ìṣíkúrò nínú èyí tí àwọn ènìyàn ti máa ń fi orílẹ̀èdè tiwọn sílẹ̀, èyí nnì ìṣípòpadà kúrò ní orílẹ̀èdè kan.

(2)  Immigration # Ìṣíwá: Èyí ni oríṣí ìṣíkúrò nínú èyí tí àwọn ènìyàn ti ń wọ orílẹ̀èdè mìíràn, èyí nnì ìṣípòpadà wà sínú orílẹ̀èdè mìíràn.

*Factors affecting migration # Àwọn olùṣe tó ń lapa lórí ìṣíkúrò*

(1)  Natural disasters # Àwọn àjálù àdámọ́: Ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn àjálù àdámọ́ bíi ẹ̀kún-omi, ìyàn, ọ̀dá àti ilẹ̀-ríri lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn ṣíkúrò níbì kan lọ sí òmíràn.

(2)  Physical conditions # Àwọn ìṣesí onímọtara: Àwọn ìṣesí onímọtara ibì kan bíi ojú-ìgbà, ilẹ̀, àti gegele lè ṣokùnfà ìṣíkúrò àwọn ènìyàn, pàápàá nígba tí irúfẹ́ àwọn ìṣesí bẹ́ẹ̀ kò bá gbeni.

(3)  Insecurity # Àìsáàbò: Ìbẹ̀rù àìsáàbò tó jẹyọ látara ogun, àìfararọ ní ti òṣèlú, abbl, lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn ṣíkúrò.

(4)  Differences in economic opportunities # Àwọn ìyàtọ̀ àǹfààní ọlọ́rọ̀ajé: Látàrí èyí, àwọn ènìyàn máa ń fẹ́ ṣílọ sí ibi tí àwọn àǹfààní ọlọ́rọ̀ajé púpọ̀ síi wà, bíi iṣẹ́ àti òwò ṣíṣe.

(5)  Changes in status # Àyípadà ìsọlọ́jọ̀: Àyípadà ìsọlọ́jọ̀, bí àpeerẹ, àkàsọ̀ gíga ní ti ẹ̀kọ́ àti ọrọ̀, lè mú kí àwọn ènìyàn ṣí kúrò ní ìgbèríko lọ sí ìgboro.

(6)  Differences in social amenities # Ìyàtọ̀ àwọn ohun amúlùúdùn: Látàrí ìyàtọ̀ nínú wíwà omi, ọ̀nà àti ẹ̀lẹ́ríríkì, àwọn ènìyàn máa ń fẹ́ ṣílọ síbi tí àwọn ohun amúlùúdùn wọ̀nyìí wà dáadáa.

*Solutions to problems of rural-urban migration # Ìyanjú ìṣòro ìṣíkúrò ìgbèríko sí ìgboro*

Ọ̀kan gbòógì nínú àwọn ìrí ìṣíkúrò tó máa ń fẹ́ fa ìṣòro ní àwọn orílẹ̀èdè tó ń dàgbàsókè ni ìṣíkúrò ìgbèríko sí ìgboro. Níwọ̀n ìgbà tí a ti mọ̀ pé ìrí ìṣíkúrò yìí jẹ́ ìṣòro gbòógì, a ti pèsè àwọn ìyanjú lójúnà àti-dènà ìṣẹ̀lẹ̀ àpọ̀jù-ènìyàn ní àwọn agbègbèe gbígbà. Àwọn ìyanjú sí àwọn ìṣoro ìṣíkúrò ìgbèríko sí ìgboro níkòósínú:

(1)  Provision of social amenities # Ìpèsè àwọn ohun amúlùúdùn: Ìpèsè àwọn ohun amúlùúdùn bíi omi, ẹ̀lẹ́tíríkì, ilée sinimọ́, ọ̀nà àti ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ ní ìgbèríko yóò rìn jìnnà láti ṣe àdínkù ìdíwọ̀n tí àwọn ọ̀dọ́ fi ń ṣílọ sí ìgboro.

(2)  Transformation of traditional agriculture to modern agriculture # Ìṣàtúndá iṣẹ́-ọ̀gbìn ìṣẹ̀ṣe sí iṣẹ́-ọ̀gbìn ìgbàlóde: Èyí yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ lè múṣẹ́ṣe nínú iṣẹ́-ọ̀gbìn ní bí ètò náà yóò ṣe sọ ọ̀gbìn di ohun tí ọkàn ń fẹ́.

(3)  Establishment of industries # Ìgbékalẹ̀ àwọn iléeṣẹ́: Ìgbékalẹ̀ àwọn iléeṣẹ́, àwọn àkànṣe-iṣẹ́ àti àwọn òwò, tí yóò gba àwọn olùgbélùú tó ń ṣiṣẹ́, tí yóò sì ṣàyípadà ìṣípòpadàa làálàá, yóò rìn jìnnà láti ṣàdínkù ìṣíkúrò ìgbèríko sí ìgboro.

(4)  Establishment of educational institutions # Ìgbékalẹ̀ àwọn ilé-ẹ̀kọ́: Ìgbékalẹ̀ àwọn kọ́lẹ́ẹ̀jì àti àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga mìíràn ní ìgbèríko yóò ṣèrànwọ́ láti ṣàdínkù ṣíṣílọ sí ìgboro.

(5)  Establishment of corporate branches # Ìgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀ka kọ́ńpìnnì: Àwọn ẹ̀ka ìjọba, iléeṣẹ́ òwò àti àwọn àgbékalẹ̀ olówónàá ni a gbọ́dọ̀ gbà níyànjú láti dá àwọn ẹ̀ka wọn sílẹ̀ ní ìgbèríko.

(6)  Provision of recreation facilities # Ìpèsè àwọn ìrọ̀rùn ìgbafẹ́: Tí a bá pèsè àwọn ìrọ̀rùn ìgbafẹ́ bíi àwọn pápá ìṣeré, adágún ìlúwẹ̀ẹ́, ilée sínimọ́ àti ọgbà ìdárayá ní ìgbèríko, èyí yóò ṣàdínkù ìfẹ́ àwọn ọ̀dọ́ wa láti ṣílọ sí ìgboro.

*~Hakeem O. Adeniyan, 12/2/2022*

*+2347034251583*



Comments

Popular posts from this blog

*MONEY EXPLAINED IN YORUBA LANGUAGE # OWÓ*

COMMERCIAL BANKS # BÁŃKÌ KÁRÀKÁTÀ

*AGRICULTURE # IṢẸ́-Ọ̀GBÌN*