LABOUR MARKET # ỌJÀ LÀÁLÀÁ
*LABOUR
MARKET # ỌJÀ LÀÁLÀÁ*
*Làálàá* ni a
lè kì gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìgbìyànjú ọmọnìyàn ní ti irú yòówù, yálà alákọ̀ọ́mọ̀ tàbí aláìlákọ̀ọ́mọ̀, àfọpọlọṣe
tàbí àfọwọ́ṣe, tí a dojú rẹ̀ kọ ìgbéjáde àwọn ire àti àwọn iṣẹ́-ìsìn.
*Ọjà* ni a lè kì
gẹ́gẹ́ bí àyè kan tàbí èyíkéyìí ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ níbi tí àwọn
olùtà àti àwọn olùrà ti ń bára wọn sọ̀rọ̀ láti ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn
ire àti àwọn iṣẹ́-ìsìn ní iyeowó-ọjà tí a pinnu nípasẹ̀ àwọn ipá ọjà.
*Ọjà làálàá* ni a lè kì gẹ́gẹ́ bí ọjà kan nínú èyí tí àwọn olùrà àti àwọn
olùtà làálàá ti máa ń ní ìbápàdé pẹ́kípẹ́kí lásìkò èyí tí a
máa ń pinnu tí a sì ń ní àdéhùn lórí àwọn owó-ọ̀yà àti àwọn ìṣesí
àwọn iṣẹ̀-ìsìn mìíràn. Làálàá ni olùṣe ìgbéjáde náà tí a
sábà máa ń rà tí a sì ń tà nínú ọjà náà.
*Labour force # Ipá làálàá*
Oríkì: Ipá
làálàá ni a lè kì gẹ́gẹ́ bí àpapọ̀ gbogbo ẹni tó wà láti pèsè
làálàá fún ìgbéjáde àwọn ire ọlọ́rọ̀ajé àti àwọn iṣẹ́-ìsìn. Ní
gbólóhùn mìíràn, ó jẹ́ àpapọ̀ iye ènìyàn tó wà ní ọjọ́-orí iṣẹ́-ṣíṣe
nínú orílẹ̀èdè kan, láwọn tí wọ́n lágbára, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́, tí
òfin sì gbà láyè láti ṣiṣẹ́.
Ipá làálàá ni àwọn olùgbélùú tó lákitiyan tàbí tó ń ṣiṣẹ́,
ó sì níkòósínú gbogbo ẹni tó ní iṣẹ́ àti àwọn tó ń wá iṣẹ́ ní ọjà
làálàá. A sábà máa ń rí wọn láàárín àkámọ́ ọjọ́-orí 18 sí 65 ọdún.
Àwọn olùgbélùú tó ń ṣiṣẹ́ yàtọ̀ láti orílẹ̀èdè kan sí òmíràn.
Àwọn ẹni tí kì í ṣe ọmọẹgbẹ́ ipá làálàá níkòósínú:
(1) Àwọn ọmọ ọjọ-orí iléèwé (0 – 17 ọdún)
(2) Àwọn àgbàlágbà (lókè 65 ọdún)
(3) Àwọn abirùn (yálà ní ti ara tàbí ní ti ọpọlọ)
(4) Àwọn ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ láti ṣiṣẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́
pé abarapá niwọ́n.
*Factors
affecting the size of labour force # Àwọn olùṣe tó ń lapa lórí títóbi ipá làálàá*
(1) Size of
population of a country # Títóbi
iye-ènìyàn orílẹ̀èdè kan: Bí iye-ènìyàn bá ṣe pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni iye
làálàá ti a óò pèsè yóò ṣe ga sí.
(2) Official
school leaving age # Ọjọ́-orí ìjáde ní
iléèwé lọ́dọ̀ ìjọba: Tí ọjọ́-orí ìjáde níléèwé bá kéré, ìbáwọ̀n
ipá làálàá yóò ga.
(3) Retirement
age # Ọjọ́-orí ìfẹ̀yìntì: Ọjọ́-orí ìjáde
kúrò lẹ́nu iṣẹ́ taráàlú yóò pinnu lórí ipá làálàá. Bí ọjọ́-orí
náà bá ṣe ga tó ni ìpèsè làálàá yóò ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni
ìdàkéjì.
(4) Pursuit of
higher education # Ilépa ẹ̀kọ́ gíga síi:
Látàrí ìlépa ẹ̀kọ́ gíga síi, ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń tayọ ọjọ́-orí ìwọlé
sínú ipá làálàá lọ́dọ̀ ìjọba.
(5) Age
structure of the population # Ìhun ọjọ́-orí
àwọn olùgbélùú: Ìhun àwọn olùgbélùú orílẹ̀èdè kan jẹ́ olùpinnu
onítumọ̀ fún títóbi ipá làálàá. Bí iye àwọn olùgbáralé bá ṣe
kéré sí ni ìpèsè làálàá yóò ṣe pọ̀ sí; bẹ́ẹ̀ náà ni ìdàkéjì.
Ní gbólóhùn mìíràn, ipá làálàá yóò lékún ní orílẹ̀èdè kan
tí púpọ̀ jù nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ bá wà láàárín ọjọ́-orí 18 àti
65 ọdún.
(6) Role of
women in the society # Ipa àwọn obìnrin
láwùjọ: Ní àwọn àwùjọ kan, a sábà máa ń kọ̀ fún àwọn obìnrin láti
kópa nínú iṣẹ́ àṣejèrè nítorí ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn, èrèdí àjùmọṣe
àti àṣà; èyí sì máa ń lapa lórí títóbi ipá làálàá.
(7) Number of
working hours and working days # Iye wákàtí
iṣẹ́ ṣíṣe àti ti ọjọ́ iṣẹ́ ṣíṣe: Iye wákàtí iṣẹ́ ṣíṣe fún ọjọ́ kan àti
iye ọjọ́ iṣẹ́ ṣíṣe nínú ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan tàbí ọdún kọ̀ọ̀kan máa ń ṣèrànwọ́
láti pinnu lórí ìpèsè làálàá.
(8) The number
of disabled # Iye aláàbọ̀-ara: Tí iye àwọn
aláàbọ̀-ara ènìyàn bá ga, pàápàá nínú àwọn olùgbélùú tó yẹ kó
máa ṣiṣẹ́, ìpèsè làálàá yóò kéré.
(9) The number
of people unwilling to work # Iye àwọn
ènìyàn tí kò fẹ́ iṣẹ́ í ṣe: *Iye pàtó kan wà nínú àwọn abarapá
ènìyàn tí àwọn náà wà láàárín àkámọ́ ọjọ́-orí 18 àti 65 ọdún, ṣùgbọ́n
tí wọn kò fẹ́ iṣẹ́ í ṣe. Tí iye wọn bá ga, èyí yóò lapa lórí
títóbi ìpèsè làálàá.
(10) Migration # Ìṣíkúrò:
Ìdíwọ̀n ìṣíkúrò lè lapa lóri títóbi ipá làálàá. Tí ìdíwọ̀n
tí àwọn olùgbélùú tó ń ṣiṣẹ́ fi ń kúrò ní orílẹ̀èdè kan bá ga
ju ìdíwọ̀n tí àwọn ènìyàn fi ń wọlé, yóò yọrí sí àdínkù nínú
ìpèsè làálàá.
(11) Trade union activities # Àwọn akitiyan ẹgbẹ́ ìṣòwò: Àwọn akitiyan ẹgbẹ́ ìṣòwò lè lapa
lórí ìpèsè làálàá. Fún àpẹẹrẹ, tí a bá fi àsìkò gúngùn sí
ìkọ́nimọ̀ọ́nṣe lórí ìṣòwò kan pàtó, èyí lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì fún àwọn
ènìyàn láti kópa nínú irúfẹ́ ìṣòwò tàbí ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ náà, tí
yóò sì yọrí sí àdínkù nínú ìpèsè làálàá.
(12) Government policies # Àwọn àlàkalẹ̀ ìjọba: Àwọn àlàkalẹ̀ ìjọba kan lè lapa lórí
ìpèsè làálàá. Fún àpẹẹrẹ, àyè ìtọ́mọ olóṣù mẹ́ta tàbí mẹ́fà
tí a máa ń fún àwọn obìnrin lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba lè ṣàdínkù ìpèsè làálàá
ní agbègbè náà.
*Efficiency of labour # Ìjáfáfá làálàá*
Oríkì: Ìjáfáfá
làálàá ni a lè kì gẹ́gẹ́ bí agbára làálàá láti ṣàlékún
àtìjáde láìsí ìṣàlékún ṣeéwọ̀n làálàá. Àlékun ìjáfáfá ni a
sábà máa ń fihàn ní àsọye àlékún àtìjáde làálàá láàárín
àsìkò kúkúrú síi láìsì ìjáwálẹ̀ nínú ìwọ̀ntayọ àwọn ire àti
àwọn iṣẹ́-ìsìn tí a gbéjáde. Tí làálàá bá jáfáfá, ìwọ̀ntayọ àwọn
ire àti awọn iṣẹ́-ìsìn tí a gbéjáde yóò ga.
*Factors
affecting efficiency of labour # Àwọn
olùṣe tó ń lapa lórí ìjáfáfá làálàá*
(1) Education
and training # Ìkọ́lẹ́kọ̀ọ́ àti ìkọ́nimọ̀ọ́nṣe:
Àkàsọ̀ ìkọ́lẹ́kọ̀ọ́ àti ìkọ́nimọ̀ọ́nṣe tí òṣìṣẹ́ kan gbà yóò rìn
jìnnà lójúnà ìṣàlékún ìjáfáfá làálàá. Òṣìṣẹ́ tí a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́
tabí tí a kọ́ mọ̀ọ́nṣe dáradára wà nípò láti ṣàlékún ìjáfáfá lẹ́nu
iṣẹ́ rẹ̀.
(2) Level of
technology # Àkàsọ̀ ìṣàmúlò-ẹ̀rọ: Ìṣàmúlò-ẹ̀rọ
gíga yóò ṣàlákún ìjáfáfá làálàá.
(3) Efficient
management # Ìdarí tó jáfáfá: Tí
ìdarí tó jáfáfá bá wà nípò nínú èyíkéyìí àgbékalẹ̀, èyí
yóò rìn jìnnà lójúnà ìmúdára síi ní ti ìjáfáfá làálàá.
(4) Personal
skill of the worker # Àkọ́mọ̀ aláraẹni ti òṣìṣẹ́
náà: Bí òṣìṣẹ́ kan bá ní àkọ́mọ̀ àdámọ́ kan ní ti ṣíṣe iṣẹ́ kan
pàtó, iṣẹ́ rẹ̀ yóò jáfáfá.
(5) Attractive
wages # Owó-ọ̀yà tó fanimọ́ra: Tí
owó-oṣù tàbí owó-ọ̀yà òṣìṣẹ́ kan bá fanimọ́ra, èyí yóò ṣàlékún
tàbí ṣègbélárugẹ ìjáfáfá òṣìṣẹ́ náà.
(6) Weather
condition # Ìṣesí ojú-ọjọ́: Àwọn ìṣesí
onímọtara tàbí tí ojú-ọjọ́ níbi iṣẹ́ kan lè lapa lórí ìjáfáfá
làálàá. Ojú-ọjọ́ gbígbóná máa ń fa ìjáfáfá làálàá wálẹ̀,
ojú-ọjọ́ tàbí àyíká tútù máa ń ṣàlékún ìjáfáfá làálàá.
(7) State of
health of worker # Ipò ìlera òṣìṣẹ́: Òṣìṣẹ́
abarapá ní àtiṣeéṣe láti jáfáfá ju òṣìṣẹ́ olókùnrùn.
(8) Efficiency
of other factors of production # Ìjáfáfá
àwọn olùṣe ìgbéjáde mìíràn: Ìjáfáfá àwọn olùṣe ìgbéjáde
mìíràn bíi ilẹ̀, ojúowó àti olùdáwọ́lé nígbà tí a bá pa wọ́n pọ̀
pẹ̀lú làálàá tó jáfáfá yóò ṣàlékún àtigbéjáde.
(9) Intelligence
of the workers # Làákàyè àwọn òṣìṣẹ́:
Àwọn òṣìṣẹ́ kan jẹ́ onílàákàyè gidi, nígbà tí àwọn mìíràn kò jẹ́
bẹ́ẹ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ onílàákàyè gidi kì í sábà ṣàṣìṣe.
(10) Conditions of service # Àwọn ìṣesí iṣẹ́-ìsìn: Ìṣesí iṣẹ́-ìsìn tí a múdára síi bíi
wíwà ìyọ̀ǹda ìrìnkèrindò, àwọn ìfà, ìtayọ-àkókò, abbl, yóò ṣèrànwọ́
láti ṣàlékún ìjáfáfá làálàá.
(11) Application of division of labour: Ìṣàmúlò pínpín làálàá: Ìṣàmúlò pínpín
làálàá àti ìlákànṣe nínú èyíkéyìí àgbékalẹ̀ lè yọrí sí
ìjáfáfá làálàá.
(12) Level of commitment and attitude # Àkàsọ̀ ìfarajì àti ìhùwàsí: Àkàsọ̀ ìfarajì
àti ìhùwàsí òṣìṣẹ́ kan lè lapa lórí ìjáfáfá làálàá. Nígbà
tí òṣìṣẹ́ kan bá farajì gidi fún iṣẹ́ rẹ̀, èyí yóò yọrí sí
ìjáfáfá làálàá.
(13) Security of job # Ààbò iṣẹ́: A lè ṣàlékún ìjáfáfá làálàá tí òṣìṣẹ́ kan bá
rí i dájú pé iṣẹ́ òun wà ní ìdáàbòbò.
(14) Promotion # Ìgbéga:
Ìgbéga lemọ́lemọ́ fún àwọn oṣìṣẹ́ ní èyíléyìí àgbékalẹ̀ lè yọrí
sí àlékún ìjáfáfá làálàá.
*Mobility of labour # Atiṣipò làálàá*
Oríkì: Àtiṣípò
làálàá ni a lè kì gẹ́gẹ́ bíi ìrọ̀rùn tí làálàá lè fi ṣípò
kúrò ní agbègbè onímọ̀ilẹ̀ kan lọ sí omíran, tàbí kúrò ní ẹnu iṣẹ́
kan lọ sí òmíràn. Làálàá ni a máa ń sọ pé ó ní àtiṣípò nígbà
tí yóò bá rọrùn fún àwọn òṣìṣẹ́ láti ṣípo kúrò ní agbègbè onímọ̀ilẹ̀
kan lọ sí òmíràn tàbí láti pààrọ̀ iṣẹ́.
*Types of mobility of labour # Oríṣìíríṣìí àtiṣípò làálàá*
Oríṣìíríṣìí àtiṣípò làálàá gbòógì méjì ló wà. Àwọn
náà ni:
(1) Geographical
mobility of labour # Atiṣípò làálàá tí
onímọ̀ilẹ̀
(2) Occupational
mobility of labour # Àtiṣípò làálàá ti
iṣẹ́
*Geographical mobility of labour # Àtiṣípò làálàá ti onímọ̀ilẹ̀*
Àtiṣípò làálàá ti onímọ̀ilẹ̀ ń tọ́ka sí ìrọ̀rùn tí àwọn òṣìṣẹ́
tàbí làálàá lè fí ṣípò kúrò ní àyè onímọ̀ilẹ̀ kan lọ sí
òmíràn ní ìlépa iṣẹ́ kannáà.
Nígbà tí òṣìṣẹ́ kan
bá ṣípò kúrò ní ìlú kan lọ sí òmíràn, bí àpẹẹrẹ, kúrò ní
Ìbàdàn lọ sí Èkó, láì pààrọ̀ iṣẹ́ tó ń ṣe, a máa ń sọ wí pé ó
ti ṣípò ní ti onímọ̀ilẹ̀. Aṣíròówó kan ní Ìbàdàn lè ṣípò lọ sí
Èkó láti tẹ̀síwájú láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi aṣíròowó.
*Factors affecting geographical mobility of
labour # Àwọn olùṣe tó ń lapa
lórí àtiṣípò làálàá ti onímọ̀ilẹ̀*
(1) Cost of
transportation # Ìnáwó ìgbérìnkèrindò:
Òṣìṣẹ́ kan lè lágbára láti ṣípò kúrò ní àyè kan lọ sí òmíràn
tí ìnáwó ìgbérìnkèrindò bá kéré. Ṣùgbọ́n tí ó bá ga, ìṣípò
yóò di ohun tó ṣòro.
(2) Accommodation
problems # Àwọn ìṣòro ìgbàsílé:
Àwọn òṣìṣẹ́ lè má nìí agbára láti ṣípò lọ sí àyè tuntun níbi tí
àwọn ìṣòro ìgbàsílé wà.
(3) Climatic
conditions # Àwọn ìṣesí ojú-ìgbà: Àwọn
òṣìṣẹ́ lè ṣípò kúrò ní ibi tí àwọn ìṣesí ojú-ìgbà rẹ̀ kò gbeni
lọ sí àwọn agbègbè tí ojú-ìgbà tó gbeni wà.
(4) Family and
cultural ties # Àsopọ̀ ìdílé àti ti àṣà:
Àwọn ọmọinú ìdílé kan tàbí ti àṣà kan lè rí i bí ohun tó ṣòro
láti ṣípò kúrò ní àyè kan lọ sí òmíràn nítorí àsopọ̀ ìdílé
tàbí ti àṣà tó yi.
(5) Government
policies # Àwọn àlàkalẹ̀ ìjọba: Àwọn
àlàkalẹ̀ ìjọba kan, fún àpẹẹrẹ, ìdásílẹ̀ Àjọ Iṣẹ́-Ìsìn Ọ̀dọ́ Ti
Orílẹ̀èdè tí à ń dàpè ní Àjọ Àgùnbánirọ̀, máa ń ṣèrànwọ́ láti
mọ̀ọ́nmọ̀ ṣípò làálàá lọ sí àwọn ìpínlẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yàtọ̀ sí àwọn
ìpínlẹ̀ orírun wọn.
(6) Social and
economic infrastructures # Àwọn
àpótí-ajé ti àjùmọ̀ṣe àti ọlọ́rọ̀ajé: Wíwà àwọn àpótí-ajé ti
àjùmọ̀ṣe àti ọlọ́rọ̀ajé, fún àpẹẹrẹ, ẹ̀lẹ́tíríkì, omi inú ọ̀pá àti
ìgbókèèrèbánisọ̀rọ̀ máa ń ṣe kóríyá fún làálàá láti ṣípò lọ
sí àwọn ibi tí àpóti-ajé wọ̀nyí wà.
(7) Discrimination
# Ẹlẹ́yàmẹ̀yà: Làálàá lè má
làágbára láti ṣípò tí ìṣeéṣe ẹlẹ́yàmẹ̀yà bá wà lòdì sí wọn ní
òpin-àjò wọn.
(8) Language
barrier # Ìdènà èdè: Nígbà tí
làálàá bá rí i ní ohun tó ṣòro láti sọ èdè agbègbè kan pàtó,
yóò di ohun tó ṣòro fún wọn láti ṣípò lọ sí irúfẹ́ agbègbè bẹ́ẹ̀.
*Occupational mobility of labour # Àtiṣípò làálàá ti iṣẹ́*
Àtiṣípò làálàá ti iṣẹ́ ń tọ́ka sí ìrọ̀rùn tí òṣìṣẹ́ kan
tàbí làálàá fi ń ṣípò kúrò lẹ́nú iṣẹ́ kan lọ sí òmíràn. Nígbà
tí òǹkọrin bá di agbábọ́ọ̀lù, ó ti pààrọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.
*Factors affecting occupational mobility of
labour # Àwọn olùṣe tó ń lapa
lórí àtiṣípò làálàá ti iṣẹ́*
(1) Cost and
length of training # Ìnáwó àti gúngùn
ìkọ́nimọ̀ọ́nṣe: Apákan àwọn ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ wọ́nwó láti ní ìkọ́nimọ̀ọ́nṣe
lórí wọn ní àsọyé àkókò àti owó, fún àpẹẹrẹ, ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ìṣègùn.
(2) Ability or
aptitude # Ìlágbára tàbí ẹ̀bun: Àwọn
iṣẹ́ kan nílò agbára àdámọ́ tàbí ẹ̀bùn, àwọn tí kò sì lẹ́bùn kò
lè yẹ lénu iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, fún àpẹẹrẹ, akọrin.
(3) Employment
prospect or age # Ìrètí tàbí ọjọ́-orí
ìgbàsíṣẹ́: Lẹ́yìn ọjọ́-orí kan pàtó (fún àpẹẹrẹ 45 ọdún) àwọn
agbanisíṣẹ́ kò ní í gba irúfẹ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀. Ìrètí agbanisíṣẹ́
lórí wọn mẹ́hẹ ní bí ìgbéayé iṣẹ́-ṣíṣe wọn ṣe kúrú.
(4) Trade
union or professional association restrictions # Àwọn ìpààlà ẹgbẹ́ ìṣòwò tàbí ẹgbẹ́ oníkọ̀ọ́ṣẹ́mọṣẹ́: Àwọn ẹgbẹ́
oníkọ̀ọ́ṣẹ́mọṣẹ́ (fún àpẹẹrẹ ìṣíròowó, ìmọ̀-òfin) nílò àwọn àmúyẹ
kan pàtó ṣáájú ìgbàwọlé.
(5) Personal
reasons # Èrèdí aláraẹni:
Ìyànláàyò aláraẹni fún iṣẹ́ kan pàtó àti àìnífẹ̀ẹ́ sí àwọn ààrọ̀
tó wà lè fa ìrẹ̀wẹ̀sí bá ìṣípò.
(6 Families
and friendly ties # Àwọn àsopọ̀ ìdílé
àti ti àwọn ọ̀rẹ́: Àsopọ̀ ọ̀rẹ́ nígbà mìíràn lè mú kí ó ṣ̀oro fún
àwọn kan láti pààrọ̀ iṣẹ́. Bákannáà, a ti mọ àwọn ìdílé kan pé wọ́n
ní í ṣe pẹ̀lú ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kan pàtó, yóò sì di ohun tó ṣòro fún ọmọínú
ìdílé náà kan láti yọra rẹ̀ kúrò nínú ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ náà.
(7) Political
instability or religious crises # Àìfararọ
ní ti òṣèlú tàbí ááwọ̀ ẹ̀sìn: Nígbà tí àìfararọ ní ti òṣèlú
tàbí ááwọ̀ ẹ̀sìn bá wà, yóò ṣòro gidi fún làálàá láti ṣípò.
(8) Wage rate
# Ìdíwọ̀n owó-ọ̀yà: Làálàá yóò ṣípò
tí àlàfo gbígbòòrò bá wà láàárín àwọn owó-oṣù, ṣùgbọ́n tí ó
bá kéré, làálàá lè má ṣìípò.
(9) Condition
of service # Ìṣesí iṣẹ́-ìsìn: Yàtọ̀
sí owó-oṣù, àwọn ìṣesí iṣẹ́-ìsìn níbi iṣẹ́ kan, fún àpẹẹrẹ, àwọn
ìfà, ìtayọ-àkókò, bọ́ọ̀sì ati ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àti ẹ̀yáwó
ilégbèé nígbà tó bá wà, yóò ṣe kóríyá fún làálàá láti má ṣìípò.
(10) Discrimination # Ẹlẹ́yàmẹ̀yà: Ẹlẹ́yàmẹ̀yà lè wà lórí akọn̄bábo, àwọ̀, ọjọ́-orí
àti ẹ̀sìn. Èyí lè lapa lórí àtiṣípò làálàá ti iṣẹ́.
*~Hakeem O. Adeniyan, 19/2/2022*
*+2347034251583*
Comments
Post a Comment