*CO-OPERATIVE SOCIETIES # ẸGBẸ́ ALÁFỌWỌ́SOWỌ́PỌ̀*


 *CO-OPERATIVE SOCIETIES # ẸGBẸ́ ALÁFỌWỌ́SOWỌ́PỌ̀*

Oríkì: A lè ki ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ẹgbẹ́ òwò alátinúwá kan nínú èyí tí ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ní ìfẹ́-ọkàn kannáà ti máa ń tu àwọn ọrọ̀ wọn jọ láti ṣe ìgbélárugẹ fún ìgbáyégbádùn ọlọ́rọ̀ajé ti àwọn ọmọẹgbẹ́ wọn nínú ìgbéjáde, ìpínká àti ìṣàmúlò àwọn ire àti àwọn iṣẹ́-ìsìn.

*Advantages of co-operative societies # Àwọn àǹfààní ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀*

(1)  Encouragement of savings # Ìwúlórí àfipamọ́: Ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ máa ń ṣe ìwúrí fún àṣà ìfipamọ́ láàárín àwọn ọmọẹgbẹ́ wọn.

(2)  Financial assistance # Ìrànwọ́ olówónàá: Wọn lè ṣa owó tí a nílò jọ fún ìdókòwò àti ìgbèrú, kí wọ́n sì pèsè ìrànwọ́ olówónàá tàbí ẹ̀yáwó fún àwọn ọmọẹgbẹ́.

(3)  Improvement of members’ standard of living # Ìmúdárasíi ní ti ìgbéayé ìpéwọ̀n àwọn ọmọẹgbẹ́: Wọn máa ń mú ìgbéayé ìpéwọ̀n àwọn ọmọẹgbẹ́ wọn dára síi nípa pípèsè àwọn ire nígbà tí wọn kò bá lágbára láti rà á fúnra wọn, bí àpẹẹrẹ, àwọn ohun ẹ̀lẹ́tíróní àti ilẹ̀.

(4)  Loan facilities from banks or government # Ìrọ̀rùn ẹ̀yáwó láti ọ̀dọ̀ báńkì tàbí ìjọba: Ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ lè rí ẹ̀yáwó gbà nírọ̀rùn ní báńkì, bí àpẹẹrẹ, báńkì aláfọwọ́sowọ́pọ̀. Wọ́n sì tún lè rí ìrànwọ́ olówónàá gbà láti ọ̀dọ̀ ìjọba.

(5)  It is democratic in nature. # Ó jẹ́ oníjọba-àwaarawa ní ti àdámọ́: Olúkúlùkù ọmọẹgbẹ́ nínú ẹgbẹ́ náà ló ní àǹfààní sí ètọ́ ẹnìkan-ìbò-kan, láìfi iye ìpín-ìdókòwò tí a ní pè.

(6)  Lower prices # Ìyeoowó-ọjà tó lọlẹ̀ síi: Ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ sábà máa ń ra àwọn ire ní kìtí lọ́dọ̀ àwọn alágbèélẹ̀rọ (manufacturers) ní iyeowó-ọjà tó dínwó síi, èyí yóò sì mú kí àwọn ọmọẹgbẹ́ náà lè ní àwọn ire yìí ní iyeowó-ọjà tó lọlẹ̀ síi.

(7)  Marketing of members’ products # Ìwátajà fún àwọn àgbéjáde àwọn ọmọẹgbẹ́: Wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọẹgbẹ́ wọn nípa ìwátajà fún àwọn àgbéjáde wọn, nípa báyìí wọn yóò rí àrídájú iyeowo-ọjà tó sàn fún àwọn àgbéjáde náà.

(8)  Elimination of middlemen # Ìyọwọ́ àwọn aláròóbọ̀: Àwọn àkitiyan ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ máa ń ṣèrànwọ́ láti ṣe ìyọkúrò àwọn aláròóbọ̀ (èyí nnì àwọn olùtodidi àti àwọn aláyọtà) àwọn tó jẹ́ pé èrè wọn ì bá kún kòkárí ìnáwó àwọn ire náà.

(9)  Prevention of exploitation # Ìdènà ìrẹ́jẹ: Ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀, pàápàá ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn aṣàmúlò, máa ń ṣèrànwọ́ láti rí i dájú pé àwọn aṣàmúlò ìgbẹ̀yìn (tí í ṣe àwọn ọmọẹgbẹ́) wà ní ìdáàbòbò.

(10)                   Encouragement of hard work # Ìmúwùúrí bá iṣẹ́ àṣekára: Àwọn ọmọẹgbẹ́ ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ sábà máa ń gba ìwúrí láti ṣiṣẹ́ kárakára nítorí àti-rí owó dá sínú ẹgbẹ́ náà.

(11)                   Strong inter-personal relationship # Ìbáṣepọ̀ àárín araẹni tó gíríkì: Nínú ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀, ìbáṣepọ̀ àárín araẹni tó gíríkì máa ń wà láàárín àwọn ọmọẹgbẹ́ nítorí pé wọ́n sábà máa ń rí ara wọn bí ọ̀kannáà.

(12)                   Education of their members # Ìkọ́lẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọẹgbẹ́ wọn: Ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ a sábà máa ṣe ìkọ́nimọ̀ọ́nṣe fún àwọn ọmọẹgbẹ́ wọn ní agbègbè ìgbéjáde, ìpínká, rírà àti títà àwọn ire àti àwọn iṣẹ́-ìsìn.

*Disadvantages of co-operative societies # Àwọn àìláǹfààní ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀*

(1)  Insufficient capital # Àìtó ojúowó: Kò sí ojúowó tító láti mú ẹgbẹ́ náà ṣiṣẹ́. Wọ́n máa ń gbáralé ìdáwó àwọn ọmọẹgbẹ́ gidigidi, èyí tí ó lè má tòó.

(2)  Inefficient management # Àìjáfáfá ìdarí: Ìgbìmọ̀ tó wà ní ìgbọ́nnú ìṣàkóso sábà máa ń níkòósínú àwọn ènìyàn tí kì í ṣe alákànṣe, tí wọ́n sì jẹ́ adarí aláàbọ̀ àkókò; nípa bẹ́ẹ̀, a lè má darí ẹgbẹ́ náà pẹ̀lú ìlapa àti ìjáfáfá.

(3)  High rate of embezzlement # Ìdíwọ̀n gíga ní ti ìkówójẹ: Púpọ̀ jùlo nínú àwọn aṣíwájú ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ jẹ́ oníbàjẹ́ gidigidi; apákan nínú wọn máa ń gùn lé ìkówójẹ àti àṣìlò owólílò tó jẹ́ ti ẹgbẹ́.

(4)  Problem of loan recovery # Ìṣòro ní ti ìgbàpadà ẹ̀yáwó: Ẹgbẹ́ náà lé má rìí ẹ̀yáwó tí a fún àwọn ènìyàn gbà padà; èyí sì lè kó àìfararọ bá ẹgbẹ́ náà. Ìgbàpadà ẹ̀yáwó máa ń ṣòro, kódà ó máa ń jẹ́ kò-ṣeéṣe ní àwọn ìgbà mìíràn.

(5)  High level of illiteracy # Àkàsọ̀ gíga ní ti àìmọ̀ọ́nkọ-mọ̀ọ́nkà: Púpọ̀ jùlọ nínú àwọn ọmọẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ máa ń jẹ́ aláìmọ̀ọ́nkọ-mọ̀ọ́nkà, irú àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò lè ní ìdásí dídára sí ìdàgbàsóke ẹgbẹ́.

(6)  Lack of initiative # Àìsí ọgbọ́n àtinúdá: Kì í sábà sí ọgbọ́n àtinúdá fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní bí ẹgbẹ́ náà ṣe máa ń fún olúkúlùkù ní ẹ̀tọ́ àti àǹfààní kannáà.

(7)  Evasion of tax # Ìsá fún owóorí: Púpọ̀ jùlọ nínú èrè àyọkù ti ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ ni a kì í sábà buwóorí lé, bíkòṣepé wọ́n máa ń pín in láàárín ara wọn ni.

(8)  Limited expansion # Ìgbèrú onígbèdéke: Àwọn ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà kò lè gbèrú látàrí ojúowó onígbèdéke tí ó wà fún wọn.

(9)  Lack of discipline # Àìsí ìbáwí: Púpọ̀ jùlọ nínú àwọn ọmọẹgbẹ́ kò ní ìbáwí ní bí wọ́n ṣe máa ń tọwọ́ bọ àwọn akitiyan tó lè fa àìṣọ̀kan láàárín àwọn ọmọẹgbẹ́.

(10)                   Government intervention # Ìdásí ìjọba: Ìjọba lè nídàásí nípasẹ̀ àwọn oríṣi ìkójàánu kan lórí àwọn ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀; èyí sì máa ń fẹ́ fa ìlọ́ra fún ìṣísẹ̀ ìdàgbàsókè àwọn ẹgbẹ́ náà.

~Hakeem O. Adeniyan, 30 Jan. 2022

+2347034251583

Comments

Popular posts from this blog

*MONEY EXPLAINED IN YORUBA LANGUAGE # OWÓ*

COMMERCIAL BANKS # BÁŃKÌ KÁRÀKÁTÀ

*AGRICULTURE # IṢẸ́-Ọ̀GBÌN*