*COMPANY # KỌ́ŃPÌNNÌ*. *PRIVATE LIMITED LIABILITY COMPANY # KỌ́ŃPÌNNÌ ÀTIJẸ̀BI ONÍGBÈDÉKE ÀDÁNI*

 

*COMPANY # KỌ́ŃPÌNNÌ*

Oríkì: A lè ki kọ́ńpìnnì gẹ́gẹ́ bíi ìgbékalẹ̀ abẹ́ òfin kan èyí tí a dásílẹ̀ láti ọwọ́ ẹgbẹ́ iye ènìyàn kan ní ìbámu pẹ̀lú òfin fún èrèdí àti-tu ojúowó jọ láti lè dá àdáwọ́lé òwò kan sílẹ̀. Kọ́ńpìnnì jẹ́ ẹni àtọwọ́dá kan, tí ó sì tayọ ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn kan lásán. Ó jẹ́ ẹni abẹ́ òfin tó ní ìláraẹni ara rẹ̀.

*PRIVATE LIMITED LIABILITY COMPANY # KỌ́ŃPÌNNÌ ÀTIJẸ̀BI ONÍGBÈDÉKE ÀDÁNI*

Oríkì: Kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke àdáni ni a lè kì gẹ́gẹ́ bí èyí tó jẹ́ pé, nípasẹ̀ àwọn oríkèé òfin rẹ̀, ó pààlà sí ẹ̀tọ́ láti tàtaré ìpín-ìdókòwò rẹ̀, ó fi gbèdéke sí iye onípìn-ín-ìdókòwò rẹ̀ láti méjì sí àádọ́ta, ó fòfinde èyíkéyìí ìpè sí àwọn aráàlú láti kówólé àwọn ìpín-ìdókòwò rẹ̀, àti pé orúkọ kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi àdáni náà gbọ́dọ̀ parí pẹ̀lú “Limited”. Àpẹẹrẹ ni Bluebird Nigeria Limited, Godwill Nigeria Limited àti Newswatch Nigeria Limited.

*Characteristics of private limited liability companies # Àwọn àbùdá kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke àdáni*

(1)  Ownership # Níni: A ni òwò náà láti ọwọ́ àwọn onípìn-ín-ìdókòwò tí iye wọn lè wà láàárín méjì àti àádọ́ta.

(2)  Objective # Èròńgbà: Àfojúsùn gbòógi fún kọ́ńpìnnì onígbèdéke àdáni ni láti jèrè.

(3)  Source of capital # Orísun ojúowó: Ojúowó tí a nílò láti bẹ̀rẹ̀ àti láti mú òwò náà ṣiṣẹ́ ni ó máa ń di pípèsè láti ọwọ́ àwọn onípìn-ín-ìdókòwò ní ìrí ìpín-ìdókòwò.

(4)  Liability # Àtijẹ̀bi: Àwọn onípìn-ín-ìdókòwò ní àtijẹ̀bi onígbèdéke. Nígbà tí ìfowódígbèsè bá fẹ́ ṣẹlẹ̀, iye tí onípìn-ín-ìdókòwò kan lè pàdánù ní gbèdéke lóri iyeorí ìpín-ìdókòwò rẹ̀ tí a ti sanwó fún ní kíkún tàbí ojúowó tí ó ti dókòwò sínú òwò náà. Òfin dáàbò bo ohun-ìní tàbí dúkìá aláraẹni rẹ̀.

(5)  Legal entity # Ìgbékalẹ̀ abẹ́ òfin: Òwò náà jẹ́ ìgbékalẹ̀ abẹ́ òfin lọ́tọ̀, ó sì yàtọ̀ sí àwọn olùni òwò náà. Òwò náà lè peni lẹ́jọ́ tàbí kí á pè é lẹ́jọ́ lórúkọ ara rẹ̀, láìfi àwọn olùni sí i.

(6)  Continuity # Ìtẹ̀síwájú: Ìtẹ̀síwájú máa ǹ wà nínú àwọn ìmuṣiṣẹ́ òwò náà nítorí pé kíkúrò tàbí ikú onípìn-ín-ìdókòwò kan lè má lapa lórí wíwà kọ́ńpìnni náà.

(7)  Shares are not easily transferable. # Àwọn ìpín-ìdókòwò kò ṣe í tàtaré nírọ̀rùn. A kò lè tún ìpín-ìdókòwò tà fún àwọn ẹlòmíràn, àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda­ àwọn onípìn-ín-ìdókòwò yòókù.

(8)  Management # Ìdarí: Kọ́ńpìnnì onígbèdéke àdáni náà ni à ń darí láti ọwọ́ àjọ àwọn apàṣẹ èyí tí àwọn onípìn-ín-ìdókòwò ti yàn.

*Sources of finance to private limited liability company # Àwọn orísun owónàá fún kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke àdáni*

(1)  Loans and overdrafts from banks # Ẹ̀yáwó àti àsanlé láti àwọn báńkì.

(2)  Shares raised by shareholders # Àwọn ìpín-ìdókòwò tí a kójọ láti ọwọ́ àwọn onípìn-ín-ìdókòwò.

(3)  Equipment leasing # Ìyáni ni àmúṣagbára: Àwọn kọ́ńpìnnì lè yáni ní àwọn àmúṣagbára bíi katakata, ọkọ̀-àjàgbé, abbl fún owó.

(4)  Retained profits # Àwọn èrè àdáró: Àwọn èrè tí kọ́ńpìnnì jẹ ni a lè yà sọ́tọ̀ tàbí bí kí á tún wọn dókòwò.

(5)  Trade credit # Ìgbàwìn ọjà: Kọ́ńpìnnì lè ra àwọn ohun-èlò atokodé láwìn.

(6)  Hire purchase # Sándíẹdíẹ: Kọ́ńpìnnì lè rí ìrọ̀rùn gbà láti rà àti láti sanwó ní díẹdíẹ.

*Advantages of private limited liability company # Àwọn àǹfààní kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke àdáni*

(1)  Large capital # Ojúowó títóbi: Kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke àdáni lè kó ojúowó jọ nírọ̀rùn látàrí àwọn onípìn-ín-ìdókòwò púpọ̀ tí ó ṣẹ̀dá òwò náà.

(2)  It is a legal entity. # Ó jẹ́ ìgbékalẹ̀ abẹ́ òfin.

(3)  Shareholders have limited liability. # Àwọn onípìn-ín-ìdókòwò ní àtijẹ̀bi onígbèdéke.

(4)  Continuity # Ìtẹ̀síwájúu wíwà: Àǹfààní ìtẹ̀síwájúu wíwà ga nítorí pé ikú tàbí kíkúrò onípìn-ín-ìdókòwò kan kò lè lapa lórí wíwà kọ́ńpìnnì náà.

(5)  There is efficient management. # Ìdarí jíjáfáfá máa ń wà.

(6)  There are large profits. # Èrè gọbọi máa ń wà.

(7)  There is possibility of expansion. # Àtiṣeéṣe ìgbèrú wà.

(8)  It enjoys internal economies of large-scale production. # Ó máa ń jẹ̀gbádùn ìṣọ́wóná abẹ́nú nítorí ìgbéjáde olóṣùwọ̀n ńlá.

*Disadvantages of private limited liability company # Àwọn àìláǹfààní kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke àdáni*

(1)  It has limited capital because the number of shareholders is limited to fifty. # Ó ní gbèdéke ojúowó nítorí pé iye onípìn-ín-ìdókòwò ní gbèdéke lórí àádọ́ta.

(2)  Shares are not sold to public. # A kò lè ta ìpín-ìdókòwò fún àwọn aráàlú.

(3)  Shares are not easily transferable. # Ìpín-ìdókòwò kò ṣe í tàtaré nírọ̀rùn.

(4)  There is no privacy because the company is required to publicise its account. # Kò sí ìdákọ́ńkọ́ nítorí pé a nílò kọ́ńpìnnì náà láti ṣe ìtẹ̀síta àsùnwọ̀n rẹ̀.

(5)  There is payment of corporate tax. # Sísan owóorí kọ́ńpìnnì wà.

(6)  There is no personal contact between the owners and the customers. # Kò sí ìfarakanra aláraẹni láàárín àwọn olùni àti àwọn oníbàárà.

(7)  There is delay in decision taking. # Ìlọ́ra máa ń wà nínú ṣíṣe ìpinnu.

~ Hakeem O. Adeniyan , 8/1/2022

+2347034251583


Comments

Popular posts from this blog

*MONEY EXPLAINED IN YORUBA LANGUAGE # OWÓ*

COMMERCIAL BANKS # BÁŃKÌ KÁRÀKÁTÀ

*AGRICULTURE # IṢẸ́-Ọ̀GBÌN*