*NIGERIAN ECONOMY # ỌRỌ̀AJÉ NÀÌJÍRÍÀ*

 *NIGERIAN ECONOMY # ỌRỌ̀AJÉ NÀÌJÍRÍÀ*

Ṣáájú dídé epo-rọ̀bì, iṣẹ́-ọ̀gbìn ló jẹ́ òpómúléró ọrọ̀ajé Nàìjíríà. Nàìjíríà ọlọ́rọ̀ epo ti rí ìdíwọ́ láti ọwọ́ àìfararọ ọ̀rọ̀ òṣèlú, ìwà-ìbàjẹ́, àìtó àpótí-ajé, àti ìdari ọlọ́rọ̀ajé ńlá-ńlá tó mẹ́hẹ. Àwọn adarí ológun tẹ́lẹ̀ ní Nàìjíríà kùnà láti sọ ọrọ̀ajé orilẹ̀èdè náà di olójú púpọ̀ yàgò fún àpọ̀jú ìgbáralé rẹ̀ lórí abala epo tó jẹ́ aládàá-ńlá ojúowó, léyìí tó ń pèsè 95% owo-àpawọlé pàṣípààrọ̀ òkèèrè àti 80% owó-àpawọléeṣẹ́ ti iṣúná. Ní ìtẹ̀lé ìdẹ̀kùn gbèsè láti ọwọ́ Ẹgbẹ́ Pàríìsì, Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ àwọn àtúntó tí a fisun ètò ìdàgbàsókè ọlọ́rọ̀ajé, ìyọkúrò ìrànwọ́, àti ìpẹ̀tù sí àwọn ááwọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn lórí ìpínká àwọn owó-àpawọlé láti agboléeṣẹ́ epo.

           Ààrẹ Goodluck Jonathan ṣàgbékalẹ̀ ikọ̀ ọlọ́rọ̀ajé tó níkòósínú àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ onírìírí àti olóókọ̀, ó sì kéde àwọn àlàkalẹ̀ láti ṣàlékún àkóyawọ́, ìpínyẹ́lẹyẹ̀lẹ ọrọ̀aje, ìdàgbà ọlọ́rọ̀ajé àti láti ṣe ìmúdárasíi olówónàá. Àìsí àpótí-ajé àti ìmuṣẹ tó lọ́ra fún àwọn àtúntò jẹ́ ìdíwọ́ pàtàkì fún ìdàgbà. Ìjọba ń ṣiṣẹ́ lójúnà ìmúdàgbàsókè àjọṣe taráàlú-tàdáni fún àwọn pópónà, iṣẹ́-ọ̀gbìn àti agbára. Gbogbo àwọn àlàkalẹ̀ yìí ni yóò ṣèrànwọ́ láti ṣàtúndá ọrọ̀ajé Nàìjíría lọ́ sí ibi gíga síi.

*Economic potentials of the Nigerian economy # Àwọn okun-àìlò ti ọrọ̀ajé Nàìjíríà*

Nàìjíríà ní okun-àìlò láti jẹ́ ọrọ̀ajé tó yára dàgbà jùlọ, àti láti tò sí ipò 13k láàárín àwọn ọrọ̀ajé 20 tó wà lókè lágbàáyé láti isinìnyìí títí di 2050, níbàámu sí ìjábọ̀ “The World in 2050” tí a gbéjáde láti ọwọ́ “Price Waterhouse Coopers, PWC’s macro-economic team”.

           Ìjábọ̀ náà wí pé pẹ̀lú àfojúsùn àgbéjáde abẹ́lé kíkún (Gross Domestic Product) tí yóò súnmọ́ $4 tírílíọ́ọ̀nù tí yóò bá fi di 2050 àti ìdíwọ̀n ìdàgbà bíi 6% àti pẹ̀lú iye ènìyàn tó ń ṣiṣẹ́ tó jẹ́ ọ̀dọ́ tó sì ń pọ̀ síi, a fojú sun Nàìjíríà láti tò sípò 13k láàárín àwọn ọrọ̀ajé tó tóbi jùlọ́ lágbàáyé tí yóò bá fi di 2050 bí ó bá lè lo okun àìlò rẹ̀ ní kíkún.

           Níbàámu sí ìjábọ̀ náà, iye ènìyàn ọjọ́orí tó ń ṣiṣẹ́, tó ń pọ̀ síi tó sì tayọ, pẹ̀lú àwọn ìdíwọ̀n agbègbè tó ń gòkè síi ní ti ìtẹ̀síwájú ìkàwé àti ìṣàmúlò-ẹrọ, ló ń wakọ̀ àfojúsọ́nà ìdàgbà oníkìmi ti Nàìjíríà.

           Ní ṣókí,

·       Nàìjíríà ní okun-àìlò ọlọ́rọ̀ajé tó dára gidi.

·       Ó ni ẹ̀bùn ọrọ̀ tó pọ̀.

·       Ó ní ipá làálàá tó pọ̀.

·       Ó ní àwọn olùdáwọ́lé tó ní ìwúrí gidi.

·       Ó ní ilẹ̀ iṣẹ́-ọ̀gbìn tó gbòòrò tó sì lọ́ràá.

·       Ó ní ọjà abẹ́le tó tóbi.

·       Ó ní àwọn aye ìgbèrí-òkun tó ní ìgbáradì tí yóò gbà á láyè láti di ilé agbára fún Áfíríkà.

*The six geopolitical zones in Nigeria # Ẹkùn ilẹ-òṣèlú mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ní Nàìjíríà*

(1)  The North-West geopolitical zone # Ẹkùn ilẹ̀-òṣèlú Àríwá-Ìwọ̀oòrùn: Àwọn ìpínlẹ̀ tí a rí nínú ẹkùn yìí ni Sókótó, Zamfara, Kebbi, Katsina, Jigawa, Kano àti Kàdúná. Àwọn akitiyan ọlọ́rọ̀ajé ẹkùn yìí ní gbòógì ni iṣẹ́-oko, ẹja-pípa, ọ̀sìn-ẹran, pàápàá mààlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́. Bákan náà ni wọ́n níkòópa nínú àwọn akitiyan agboléeṣẹ́ bíi ìwakùṣà, fún àpẹẹrẹ, òkúta-ẹfun ní Sókótó.

(2)  The North-East geopolitical zone # Ẹkùn ilẹ̀-òṣèlú Àríwá-Ìlàoòrùn: Ẹkùn yìí níkòósínú àwọn ìpínlẹ̀ wọ̀nyí: Yobe, Borno, Bauchi, Gombe, Adamawa àti Taraba. Àwọn akitiyan ọlọ́rọ̀ajé gbòógì ti ẹkùn yìí ni iṣẹ́-oko, ẹja-pípa, ìgbéjáde ẹran-ọ̀sìn, pàápàá mààlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́. Wọ́n sì tún níkòópa nínú àwọn akitiyan ìwakùṣà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Ẹkùn yìí ló ní ẹbùn àdámọ́ ní ti ọrọ̀ àlùmọ́nì tó kéré jùlọ.

(3)  The North-Central geopolitical zone # Ẹkùn ilẹ̀-òṣèlú Àríwá-Àárín-gbùngbùn: Ẹkùn yìí ló ń ṣojú agbègbè àárín Nàìjíríà pẹ̀lú ìkósínú àwọn ìpínlẹ̀ Benue, Kogi, Nasarawa, Niger, Plateau àti Kwara. Agbègbè Olúùlú Àpapọ̀ tí í ṣe Abuja náà wà ní ẹkùn yìí. Àwọn akitiyan gbòógì ní ẹkùn yìí ni iṣẹ́-oko, ẹja-pípa, iṣẹ́-ọdẹ, ìṣòwò, aṣọ-híhun, iṣẹ́-àgbẹ̀de, iṣẹ́-àdìrẹ àti ẹní-híhun. Idí tí àwọn akitiyan ọlọ́rọ̀aje ẹkùn yìí fi jẹ́ iṣẹ́-oko àti ẹja pípa ni pé wọ́n ní ilẹ̀ ọlọ́ràá àti odò Ọya pẹ̀lú odò Benue. Bákan náà ni wọ́n ń kópa nínú àwọn akitiyan ìwakùṣà tínìn àti kòlóńbáìtì ní Jos, wúrà àti irin-tútù ní Kogi àti okúta-ẹfun ní Ìpínlẹ̀ Benue. Bákan náà ni a rí agbára olómidẹ̀lẹ́tíríkì ní ẹkùn yìí, fún àpẹẹrẹ, Ìsédò Káínjí.

(4)  The South-West geopolitical zone # Ẹkùn ilẹ̀-òṣèlú Gúúsù-Ìwọ̀oòrún: Ẹkùn yìí níkòósínú àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó ń sọ èdè Yorùbá. Àwọn ìpínlẹ̀ náà ni Èkó, Ògùn, Ọ̀yọ́, Oǹdó, Èkìtì àti Ọ̀ṣun. Ẹkùn yìí ní ẹ̀bùn akitiyan iṣẹ́-ọ̀gbìn àti ti káràkátà pẹ̀lú. Ẹkùn yìí ń kópa nínú iṣẹ́-oko pàápàá àwọn ire-oko igi bíi kòkó, rọ́bà, obì, ọ̀pẹ, àti àwọn akitiyan ẹran-ọ̀sìn bíi ọ̀sìn-adìẹ àti ọ̀sìn-ẹlẹ́dẹ̀. Ẹkùn yìí tún ń kópa nínú akitiyan ìwakùsà bíi òkúta-ẹfun ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.

(5)  The South-East geopolitical zone # Ẹkùn ilẹ̀-òṣèlú Gúúsù-Ìlàoòrùn: Ẹkùn yìí níkòósínú àwọn ìpínlẹ̀ márààrún tó ń sọ èdè Ìgbò. Àwọn ìpínlẹ̀ náà ni Anambra, Imo, Enugu, Abia àti Ebonyi. Àwọn akitiyan ọlọ́rọ̀ajé gbòógì ẹkùn yìí ni iṣẹ́-oko lóri àwọn ire-oko jíjẹ bíi iṣu, ẹ̀gẹ́, ìrẹsì, abbl. Bákan náà ni wọ́n ń kópa nínú àwọn akitiyan ìwakùsà ní ti èédú, epo-rọ̀bì, òkúta-ẹfun abbl. A mọ ẹkùn yìí sí ìṣòwò tó bùháyà àti ìṣàgbélẹ̀rọ lábẹ́lé ní Ìpínlẹ̀ Abia àti Anambra.

(6)  The South-South geopolitical zone # Ẹkùn ilẹ̀-òṣèlú Gúúsù-Gúúsù: Ẹkùn yìí níkòósínú àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó ń gbépo jáde ní Niger Delta. Àwọn yìí ni Edo, Delta, Rivers, Bayelsa, Cross River àti Akwa-Ibom. Àwọn akitiyan ọlọ́rọ̀ajé gbòógì ẹkùn yìí níkòósínú ìgbéjáde epo-rọ̀bì, òkúta-ẹfun ní Edo àti irin-tútù ní Delta. Bákan náà ni wọ́n ń kópa nínú ọ̀gbìn irè-oko bíi kòkó, ọ̀pe, obì, rọ́bà, abbl, àti ẹja-pípa látàrí ibi tí wọ́n wà ní Niger-Delta. Àwọn akitiyan ọlọ́rọajé mìíràn ní ìṣòwò, iṣẹ́-báńkì, èbútékun, abbl.

~Hakeem O. Adeniyan, 17/3/2022

+2347034251583

Comments

Popular posts from this blog

*MONEY EXPLAINED IN YORUBA LANGUAGE # OWÓ*

COMMERCIAL BANKS # BÁŃKÌ KÁRÀKÁTÀ

*AGRICULTURE # IṢẸ́-Ọ̀GBÌN*