PARTNERSHIP # ÀJỌṢE
*PARTNERSHIP
# ÀJỌṢE*
Oríkì: A lè ki àjọṣe gẹ́gẹ́ bíi irú ìgbékalẹ̀ òwò kan nínú
èyí tí ẹni méjì sí ogún ti ṣàdéhùn lábẹ́ òfin láti dásílẹ̀ àti
láti darí ìgbékalẹ̀ òwò kan pẹ̀lú àfojúsùn kan ṣoṣo láti jèrè.
A aṣ́abà máa ń ṣẹ̀dá àjọṣé láti ọwọ́ ẹgbẹ́ ẹni méjì sí ogun, lawọn
tí wọ́n ti ṣàdéhùn, lọ́pọ̀ ìgbà lábẹ́ òfin, láti tu àwọn ọrọ̀ wọn jọ
tàbí àkọ́mọ̀ wọn tàbí méjèèjì àti láti ṣe ìdásílẹ̀ àdáwọ́lé
òwò kan. Àwọn tó kópa nínú àdéhùn àjọṣe ni à ń pè ní alájọṣe.
Awọn alájọṣe máa ń jùmọ pín èrè, àdánù àti ewú inú òwò náà.
Nígbà tí àwọn alájọṣe bá kópa nínú àdáwọ́lé iṣẹ́ báńkì, iye ẹni tí a nílò lábẹ́
òfin wà láàárín méjì sí mẹ́wàá. Díẹ̀ lára àpẹẹrẹ àjọṣe ní
Nàìjíríà ni Gani Fawẹhinmi and Co. (Law chamber), Diya
Fatimilehin and Co. (estate firm).
*Advantages
of partnership # Àwọn àǹfààní àjọṣe*
(1) Sufficient
capital # Ojúowó tító: Àjọṣe ní
àwọn ọrọ owónàá púpọ̀ ju ìjólùni ẹlẹ́nìkan nítorí pé àwọn
ènìyàn púpọ̀ síi ló ń kópa, látàrí bẹ́ẹ̀ ojúowó púpọ̀ síi ni
yóò di kíkójọ nípasẹ ìdáwó àwọn alájọṣe.
(2) Increase
in production # Àlékún ìgbéjáde
(3) Joint
decision making # Ìpinnu àjùmọ̀ṣe: Àwọn
àbọ̀ dídára síi ló máa ń jáde nígbà tí àwọn alájọṣe méjì tàbí
jù bẹ̀ bá pa ìmọ̀ pọ̀ tí wọ́n sì jùmọ̀ ṣe àwọn ìpinnu fún àdáwọ́lé
náà.
(4) There is
privacy # Ìdákọ́ńkọ́ máa ń wà: Ìdákọ́ńkọ́
máa ń wà nítorí pé àwọn alájọṣe kò sí lábẹ́ kàn-ńpá òfin láti ṣe
ìtẹ̀jáde àwọn àsùnwọ̀n olọ́dọọdún wọn fún ìṣamúlò aráàlú.
(5) Better
management # Ìdari dídára síi: Nípa
kíkópapọ̀ àwọn àkọ́mọ̀ àti mímọ̀ọ́ṣe, àwọn òwò àjọṣe a sábà máa ṣe
í darí ju òwò ẹlẹ́nìkan.
(6) Sharing of
risks and liabilities # Pínpín ewu
àti àtijẹ̀bi: Àwọn alájọṣe máa ń jùmọ̀ pín ewu àti àtijẹ̀bi, tí èyi
sì máa ń mú àdínkù bá àjàgà olúkúlùkù.
(7) Better
chance of continuity # Àǹfààní dídára
síi láti tẹ̀síwájú: Àǹfààní dídárá síi wà fún ìtẹ̀síwájú
nítorí pé ikú tàbí ìkúrò alájọṣe kan lè má yọrí sí òpin òwò
náà.
(8) No legal
formalities required # A kò nílò ọ̀fíntótó
òfin: Láti ṣe ìdásílẹ̀ àjọṣe, a kò nílò ìrínàjò gbòógì fún
ìgbékàlẹ̀, kò rí bíi ti kọ́ńpìnnì.
(9) Increased
efficiency # Ìjáfáfá púpọ̀ síi
(10)
Specialisation in management # Ìlákànṣe nínú ìdarí: Àlàkalẹ̀ pínpín
làálàá máa ń di mímúlò nínú ètò onípòjipò onídarí àti oníṣakóso
ti òwò náà.
(11)
Greater possibility of expansion # Àtiṣeéṣe ìgbèrú gíga síi: Àtiṣeéṣe ìgbèrú wà
nípa lílo àfikún ojúowó tí a rí gbà lọ́wọ́ àwọn alájọṣe tó ṣẹ̀ṣẹ̀
ń darapọ̀.
(12)
Loan facilities # Ìrọ̀rùn ẹ̀yáwó: Àjọṣe lè rí ẹ̀yáwó gbà nírọ̀rùn lọ́dọ àwọn
ayánilówó níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ṣe ni àwọn alájọṣe jùmọ̀ ni àtijẹ̀bi.
A lè lo ẹ̀yáwó náà fún ìgbèrú òwò náà.
*Disadvantages
of partnership # Àwọn àìláǹfààní àjọṣe*
(1) Unlimited
liability # Àtijẹ̀bi aláìnígbèdéke:
Àwọn alájọṣe ló ni àtijẹ̀bi gbèsè òwò àjọṣe náà títí dórí
títóbi dúkìá wọn ní kíkún.
(2) Business
is not a legal entity. # Òwò náà
kì í ṣe ìgbékalẹ̀ abẹ́ òfin: kò lè peni lẹ́jọ́, a kò sì lè pè é lẹ́jọ́
ní orúkọ ara rẹ̀.
(3) Limited
growth # Ìdàgbà onígbèdéke:
Ìdàgbà àjọṣe náà ní gbèdéke lábẹ́ mímọ̀ọ́ṣe onídarí ti àwọn alájọṣe
náà.
(4) Disagreement
between partners can end the business. # Àìgbọ́rayé
láàárín àwọn alájọṣe lè fòpin sí òwò náà.
(5) Risk of
dissolution # Ewu ìtúká: Ikú, ìyawèrè
àti ìjẹgbárun alájọṣe kan lè mú òwò náà wá sí òpin òjijì.
(6) Difficulty
in management # Ìṣòro nínú ìdarí: Níwọ̀n
ìgbà tó jẹ́ pé olúkúlùkù alájọṣe ni yóò fẹ́ wí tiẹ̀, àti-ṣèpinnu
lè lọ́ra kó sì pẹ́.
(7) False
records # Àwọn àkọsílẹ̀ èké:
Apákan àwọn alájọṣe náà, pàápàá àwọn alájọṣe alákitiyan, le lo àkọsílẹ̀
èké láti jẹ àwọn àǹfààni kan lórí àwọn yòókù.
(8) Inability
to raise sufficient capital # Àìlè kó
ojúowó tító jọ
(9) Action of
one partner is binding on others. # Ìgbésẹ̀
alájọṣe kan de àwọn yòókù. Alájọṣe kan lè fa àwọn yòókù rẹ̀ sínú
ìṣòro látàrí àìkíyèsára rẹ̀. Nípa báyìí, òwò náà lè foríṣánpọ́n.
~Hakeem O. Adéníyan, 5/1/2022
+2347034251583.
Comments
Post a Comment