*POPULATION CENSUS # ÌKÀNÌYÀN*
*POPULATION
CENSUS # ÌKÀNÌYÀN*
A lè kì ìkànìyàn gẹ́gẹ́ bí òǹkà oríòjorí gbogbo ọmọ orílẹ̀èdè
kan ní àkókò kan pàtó. Ó tọ́ka sí òǹkà láti ọwọ́ ìjọba ní ti àwọn
ọmọkùnrin, àwọn ọmọbìnrin, àwọn géńdékùnrin àti àwọn géńdébìnrin,
tó fi mọ́ àwọn aláàbọ̀-ara, nínú orílẹ̀èdè kan ní àsìkò kan
pàtó.
A sábà máa ń ṣe ìkànìyàn ní ọdún mẹ́wàá mẹ́wàá. Nígbà tí a
bá ti ṣe ọ̀wọ́ àwọn ìkànìyàn kan dáradára, ó máa ń padà rọrùn
síi, nípa lílo ìdíwọ̀n ìdàgbà, láti diyelé iye-ènìyàn láàárín
àsìkò àwọn òǹkà náà.
Ìkànìyàn máa ń pèsè ìwífúnni nípa ọjọ́orí, akọn̄bábo, iṣẹ́èṣe
àti ibùgbé.
*Importance of population census # Pàtàkì ìkànìyàn*
(1) Population
size # Títóbi iye-ènìyàn:
Ìkànìyàn máa ń ṣèrànwọ́ fún ìjọba láti mọ iye ẹni tó ń gbé orílẹ̀èdè
àti ìhun (structure) àwọn olùgbélùú.
(2) Revenue
estimates # Ìdíyelé owó-àpawọléeṣẹ́:
Ó máa ń ṣèrànwọ́ láti pinnu lórí àwọn géńdé tó ṣe í buwóorí lé
lójúnà àti-mọ iye owó-àpawọléeṣẹ́ tí a óò máa retí ní abala náa.
(3) Forecast
of future economic needs # Àsọtẹ́lẹ̀
àwọn bùkátà ọlọ́rọ̀ajé ọjọ́ọwájú, bí àpẹẹrẹ ilégbèé àti oúnjẹ.
(4) Determination
of the level of unemployment # Ìpinnu
lórí àkàsọ̀ àìníṣẹ́: Ìkànìyàn máa ń pèsè òǹkádẹ̀rí fún ìjọba
láti pinnu lórí àkàsọ̀ àìníṣẹ́ lórílẹ̀èdè.
(5) Determination
of standard of living # Ìpinnu
lórí ìgbéayé ìpéwọ̀n: Ìkànìyàn tún máa ń ṣèrànwọ́ láti pinnu
lórí ìgbéayé ìpéwọ̀n ní ti àwọn ènìyàn orílẹ̀èdè kan nípasẹ̀
owó-àpawọlé orí kọ̀ọ̀kan.
(6) Formulation
of economic policies # Ìṣàgbékalẹ̀ àwọn àlàkalẹ̀
ọlọ́rọ̀ajé: Iye-ènìyàn inú orílẹ̀èdè kan ni a máa ń lò láti ṣàgbékalẹ̀
àwọn àlàkalẹ̀ ọlọ́rọ̀ajé. Bí àpẹẹrẹ, àgbékalẹ̀ owó-àpawọlé nígbà
mìíràn la máa ń gbé lórí àwọn fígọ̀ iye-ènìyàn.
(7) Number of
immigrants # Iye àwọn aṣíwá: Iye àwọn aṣíwá
ní orílẹ̀èdè kan ni a lè mọ̀ tàbí díyelé ní gbígbé lórí
iye-ènìyàn.
(8) Distribution
of resources # Ìpínká àwọn ọrọ̀:
Ìkànìyàn máa ń ṣèrànwọ́ fún ìjọba lórí ìpínká àwọn ọrọ̀. Bí
àpẹẹrẹ, àwọn agbègbè oníye-ènìyàn púpọ̀ bíi Èkó àti Kánò yóò
rí ọrọ̀ púpọ̀ gbà ju àwọn agbègbè oníye-ènìyàn kékeré.
(9) It helps
the government to provide social amenities # Ó máa ń ṣèrànwọ́ fún ìjọba láti pèsè àwọn ohun amúlùúdùn.
(10)
Determination of population density # Ìpinnu lórí dídí àwọn olùgbélùú: Ó máa ń ṣèrànwọ́
fún ìjọba láti mọ àwọn agbègbè orílẹ̀èdè níbi tí iye-ènìyàn fún
agbègbè ilẹ̀ ti ga tàbí kéré.
(11)
It reveals level of manpower # Ó ń ṣàfihàn àkàsọ̀ àpapọ̀ òṣìṣẹ́: Ó ń ṣèrànwọ́
láti ṣàfihàn àpapọ̀ iye àwọn ẹni tó ń ṣiṣẹ́.
(12)
Giving of aids # Ìfúnni ní àrànṣe: Ìkànìyàn máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn àjọ
àgbáyé àti àwọn ìjọba lórí ìfúnni ní àrànṣe àti ìrànwọ́
mìíràn ní àwọn orílẹ̀èdè.
(13)
Investment decisions # Ìpinnu ìdókòwó: Ó máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn olùdókòwò
àgbáyé láti ṣe ìpinnu ìdókòwò. Ọ̀pọ̀ olùdókòwò àgbáyé ní ìfẹ́-ọkàn
sí àti-bẹ̀rẹ̀ òwò ní Nàìjíríà nítorí iye-ènìyàn rẹ̀ tó pọ̀.
(14)
Allocation of parliamentary seats # Pínpín àga iléègbìmọ̀ aṣòfin: Iye-ènìyàn ní a
sábà máa ń lò ní Nàìjíríà láti pín àwọn àga iléègbìmọ̀ aṣòfin.
Àwọn ìpínlẹ̀ tó ní iye-ènìyàn púpọ̀ ni a máa ń fún ní àwọn àga
iléègbìmọ̀ aṣòfin púpọ̀ ju àwọn ìpínlẹ̀ tó ní iye-ènìyàn kékeré.
*Problems associated with population census # Àwọn ìṣòro tó ní í ṣe pẹ̀lú ìkànìyàn*
(1) High level
of illiteracy # Àkàsọ̀ gíga ní ti àìmọ̀ọ́nkọ-mọ̀ọ́nkà:
Àwọn ìwífúnni tí a máa ń rí gbà lọ́dọ̀ àwọn aláìmọ̀ọ́nkọ-mọ̀ọ́nka
sábà máa ń jẹ́ irọ́ àti aṣinilọ́nà.
(2) High cost
# Ìnáwó ńlá: Iye owo gọbọi la mán ń
lò láti ṣètò ìkànìyàn.
(3) Political
problem # Ìṣòro ọ̀rọ̀-òṣèlú: Níwọ̀n
ìgbà tó jẹ́ pé ìkànìyàn ni a máa ń lò láti pín àwọn ọrọ̀ sí àwọn
ìpínlẹ̀ orílẹ̀èdè, àwọn fígọ̀ ìkànìyàn ni a sábà máa ń ṣèké
sí láti mú kí àwọn ìpínlẹ̀ kan jèrè àwọn ọrọ̀ ju àwọn ìpínlẹ̀
mìíràn.
(4) Geographical
barriers # Àwọn gàgá onímọ̀-ilẹ̀:
Púpọ̀ jùlọ nínú àwọn ìletò ni kò ṣe í dé nítorí òkè,
àfonífojì, odo, abbl. Èyí mú kí ìkànìyàn ṣòro ní àwọn agbègbè
yìí.
(5) Lack of
trained personnel # Àìsí àwọn òṣìṣẹ́
alákọ̀ọ́mọ̀ọ́nṣe: Àwọn òṣìṣẹ́ alákọ̀ọ́mọ̀ọ́nṣe bíi àwọn akànìyàn ni a
kì í rí nírọ̀rùn. Fún ìdí èyí lílò àwọn òṣìṣẹ́ aláìkọ́mọ̀ọ́nṣe
láti ṣètò ìkànìyàn máa ń yọrí sí àwọn àbọ̀ aláìṣegẹ́gẹ́.
(6) Religious
believes # Ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn: Ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn
àwọn kan jẹ́ ìṣòro gbòógí tí a máa ń bápàdé lásìkò ìkànìyàn.
(7) Lack of
transportation # Àìsí ìgbérìnkèrindò: Ọ̀pọ̀
àwọn agbègbè ìgbèríko kò ní ọ̀nà tó ṣe í fọkọ̀ rìn, èyí sì máa
ń dènà tàbí fa ìdíwọ́ fún àwọn olùkà láti dé àwọn ìletò kan.
(8) Lack of
communication facilities # Àìsí ìrọ̀rùn
ìbáraẹnisọ̀rọ̀: Àwọn ìrọ̀rùn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó mẹ́hẹ tàbí tí kò sí
rárá máa ń mú kí ìkànìyàn ṣòro gidi, pàápàá ní àwọn agbègbè
ìgbèríko.
(9) Poor
regional planning # Àlàkalẹ̀ agbègbè tó
mẹ́hẹ: Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìlú àti àwọn abúlé ní a kò àlàkalẹ̀ rẹ̀. Lọ́pọ̀lọpọ̀
ìgbà, àwọn ilé máa ń fọ́nká, apákan nínú wọn kò sì ní nọ́ńbà.
Èyí máa ń mú kó ṣòro fún àwọn òṣìṣẹ́ ìkànìyàn láti ṣètò
ìkànìyàn aláṣeyọrí.
(10)
Tax evasion # Ìsá fún owóorí: Látàrí àkàsọ̀ gíga ní ti àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́nkà
àti àìmọ̀kan, àwọn ènìyàn sábà máa ń pèsè ìwífúnni èkè
lásíkò ìkànìyàn pẹ̀lú ìgbagbọ́ pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ kíkún yóò yọrí
sí sísan owóorí tó ga.
~Hakeem O. Adeniyan, 4/2/2022
+2347034251583
Comments
Post a Comment