*PUBLIC CORPORATION # ÀJỌ TARÁÀLÚ*


 *PUBLIC CORPORATION # ÀJỌ TARÁÀLÚ*

Oríkì: Àjọ taráàlú, tí a tún mọ̀ sí àdáwọ́lé taráàlú tàbí àjọ oníbàámu òfin, ni a lè kì gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ òwò olóṣùwọ̀n ńlá kan tí a dásílẹ̀, tí a ni, tí a sì fún ní owónàá láti ọwọ́ ìjọba orílẹ̀èdè kan, ní pàtàkì láti pèsè àwọn iṣẹ́-ìsìn fún àwọn aráàlú.

À ń mú àwọn àjọ taráàlú ṣiṣẹ́ láti ọwọ́ ìjọba nípasẹ̀ owó-orí tí àwọn ènìyàn san. A gbé wọn kalẹ̀ nípa òfin-àmúṣe ti ìgbìmọ̀ aṣòfin tàbí àṣẹ́-dòfin. À ń kójàánú àjọ taráàlú láti ọwọ́ ìgbìmọ̀ àwọn apàṣẹ tí ìjọba ti yàn. A kò gbé e kalẹ̀ láti jèrè ṣùgbọ́n láti pèsè àwọn àkànṣe iṣẹ́-ìsìn fún àwọn aráàlú.

Àpẹẹrẹ àjọ taráàlú ni: Nigerian Ports Authority (N.P.A.), Nigerian Railway Corporation (N.R.C.), Federal Radio Corporation of Nigeria (F.R.C.N.) àti Nigerian Communication Commission (N.C.C).

*Advantages of public corporation # Àwọn àǹfààní àjọ taráàlú*

(1)  Provision of infrastructural facilities # Ìpèsè àwọn àpótí-ajé: Àwọn àjọ taráàlú máa ń pèsè àwọn àpótí-ajé bíi òpópónà, iléèwé, ojúurin, àti ẹlẹ́tíríkì, fún àwọn olùgbélùú.

(2)  Availability of large capital # Wíwà ojúowó gọbọi: Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ìjọba ló ni àwọn àdáwọ́lé taráàlú, ojúowó tító máa ń wà ní gbogbo ìgbà fún àrídájú ìmúgbòòrò àwọn àdáwọ́lé náà.

(3)  There is continuity # Ìtẹ̀síwájú máa ń wà.: Àwọn àjọ taráàlú máa ń wà fún àsìkò pípẹ́.

(4)  Development of capital projects # Ìmúdàgbàsókè àwọn àkànṣe-iṣẹ́: Ìgbékalẹ̀ àwọn àjọ taráàlú máa ń mú ìdàgbàsókè bá àwọn àkànṣe-iṣẹ́ pàtàkì, àpẹẹrẹ ni ìfanásí ìgbèríko.

(5)  Avoidance of exploitation of consumers # Ìyàgò fún ìrẹ́jẹ àwọn aṣàmúlò: Àwọn àjọ taráàlú sọjí sí ọ̀rọ̀ àwọn aṣàmúlò bí wọ́n ṣe ń rí i dájú pé àdínkù bá ìrẹ́jẹ àwọn aṣàmúlò jọjọ.

(6)  Creation of higher standards # Ìdásílẹ̀ àwọn ìpéwọ̀n gíga síi: Ìjọba máa ń wọnú òwò fún àrídájú àwọn ìpéwọ̀n gíga síi, àpẹẹrẹ ni ìpèsè àwọn ohun ìrọ̀rùn ti ẹ̀kọ́.

(7)  Accountability to the public # Ìṣèṣíròoṣẹ́ fún aráàlú: Àwọn àdáwọ́lé taráàlú máa ń ṣíròoṣẹ́ fún aráàlú nítorí pe wọ́n gbọ́dọ̀ jọ̀wọ́ àwọn ìjábọ̀ ọlọ́dọọdun wọn fún ìgbìmọ̀ aṣòfin.

(8)  Legal entity # Ìgbékalẹ̀ abẹ́ òfin: Àjọ taráàlú jẹ́ ìgbékalẹ̀ abẹ́ òfin. Ó lè peni lẹ́jọ́, a sì lè pè é lẹ́jọ́ lórukọ ara rẹ̀.

(9)  It caters for the interest of workers # Ó máa ń bójútó ìfẹ́-ọkàn àwọn òṣìṣẹ́.

(10)                   It provides employment opportunities. # Ó máa ń pèsè àǹfààní ìgbanisíṣẹ́.

(11)                   Enjoyment of large-scale production # Ìgbádùn ìgbéjádé olóṣùwọ̀n ńlá: Látàrí wíwà ojúowó gọbọi fún ìgbèrú, ìgbéjádé yóò dára síi, yóò sì lékún.

(12)                   Generation of revenue # Ìgbéjádé owó-àpawọléeṣẹ́: Owó-àpawọléeṣẹ́ máa ń di gbígbéjáde láti ọwọ́ ìjọba nípasẹ̀ àwọn àjọ taráàlú láti pèsè owónàá fún àwọn àkànṣe-iṣẹ́ yòókù.

*Disadvantages of public corporations # Àwọn àìláǹfààní àjọ taráàlú*

(1)  It requires large capital to establish. # Ó nílò ojúowó gọbọi láti gbékalẹ̀.

(2)  Government interference # Ìdásí ìjọba: Ìjọba lè dásí akitiyan àwọn àdáwọ́lé taráàlú nípasẹ̀ yíyan àwọn ẹni tí kò yẹ, tí kò sì dáńgájíá gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ìgbìmọ̀ apàṣẹ.

(3)  Inefficiency in operation # Àìjáfáfá nínú ìmúṣiṣẹ́: Àìsí ìfigagbága lè fa àìjáfáfá nínú ìmúṣiṣẹ́ òwò náà.

(4)  Danger of monopoly # Ewu ànìkànjọpọn: Àwọn àjọ taráàlú máa ń jẹ́ anìkànjọpọ́n níti adámọ́, nípa báyìí, wọ́n lè ṣi àǹfààní náà lò.

(5)  Bureaucratic procedures # Àwọn ìrìn-àjò ìṣàkóso: Ṣíṣe ìpinnu lè lọ́ra nítori ó níláti kọjá níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn tàbí ọ̀pọ̀ ìkànnì ṣáájú ìfọwọ́sí.

(6)  Corruption and mismanagement # Ìwà ìbàjẹ́ àti àṣìdarí: Ọ̀pọ̀ àwọn àdáwọ́lé taráàlú ní Nàìjíríà ló ti di oríkò pàtàkì fún ìkówójẹ àti àṣìdarí àwọn ọrọ̀ orílẹ̀èdè.

(7)  Not profitable # Kò lérè: Púpọ̀ júlọ nínú àwọn àdáwọ́lé taráàlú ni à ń mú ṣiṣẹ́ lórí àdánù nítorí wọ́n tóbi jù, wọ́n sì díjú jù láti dari.

(8)  Wastage # Ìfiṣòfò: Nínú àwọn àdáwọ́lé taráàlú, a kì í sábà fúnlẹ̀ mọ́ ìfiṣòfò nítorí ìgbàgbọ́ pé àwọn olùsanwóorí ni yóò fara gbá àwọn àdánù náà.

(9)  Lack of initiative # Àìsí ọgbọ́n àtinúdá: Àìsí ọgbọ́n àtinúdá sábà máa ń farahàn nínú àwọn àdáwọ́lé taráàlú ní bí àwọn aṣojú ìjọba ṣe níláti buwọ́lu àwọn ètò àti àwọn àlàkalẹ̀ ìgbékalẹ̀ náà.

(10)                   Lack of privacy # Àìsí ìdákọ́ńkọ́: Níwọ̀n ìgbà tí a níláti tí ìjábọ̀ ọlọ́dọọdún síta fún àwọn aráàlú, irú àwọn àjọ bẹ́ẹ̀ kò ní ìdákọ́ńkọ́ ara wọn.

~Hakeem O. Adeniyan, 23/1/2022

+2347034251583

Comments

Popular posts from this blog

*MONEY EXPLAINED IN YORUBA LANGUAGE # OWÓ*

COMMERCIAL BANKS # BÁŃKÌ KÁRÀKÁTÀ

*AGRICULTURE # IṢẸ́-Ọ̀GBÌN*