PUBLIC LIMITED LIABILITY COMPANY (OR JOINT STOCK COMPANY) # KỌ́ŃPÌNNÌ ÀTIJẸ̀BI ONÍGBÈDÉKE TARÁÀLÚ (TÀBÍ KỌ́ŃPÌNNÌ OWÓ-ÌDÓKÒWÒ ÀJODÁ)
*PUBLIC
LIMITED LIABILITY COMPANY (OR JOINT STOCK COMPANY) # KỌ́ŃPÌNNÌ ÀTIJẸ̀BI ONÍGBÈDÉKE TARÁÀLÚ (TÀBÍ KỌ́ŃPÌNNÌ
OWÓ-ÌDÓKÒWÒ ÀJODÁ)*
Oríkì: Kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke taráàlú ni a lè kì,
nípasẹ̀ àwọn oríkèé òfin rẹ̀, bíi èyí tí ó fàyè gba àwọn
aráàlú láti kówólé àwọn ìpín-idókòwò rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ ní ó kéré
tán ẹni méje tí kò sì sí iye ẹni tó pọ̀jù tí a là sílẹ̀, ó fàyè
gba àwọn ìpín-ìdókòwò náà láti ṣe í tàtaré, àti pé, orúkọ kọ́ńpìnnì
àtijẹ̀bi onígbèdéke taráàlú náà gbọ́dọ̀ parí pẹ̀lú ìgékúrú “plc”.
Ọ̀rọ̀ “taráàlú” ni a máa ń lò láti túmọ̀ sí pé ẹnikẹ́ni nínú
àwọn aráàlú ló ní òmìnira láti ra àwọn ìpin-ìdókòwò nínú òwò
náà nígbà tí a bá polówó àwọn ìpín-ìdókòwò fún títà. Ní ti
òdodo, àwọn aládàáni àti àwọn ìgbékalẹ̀ ló ni kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi
onígbèdéke taráàlú.
Kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke taráàlú tàbí kọ́ńpìnnì
owó-ìdókòwò àjọdá jẹ́ ìgbékalẹ̀ abẹ́ òfin lọ́tọ̀. Lábẹ́ òfin a kà
á kún pé ó ní ìdámọ̀ ti ara rẹ̀. Àwọn onípìn-ín-ìdókòwò kò lè
dáhùn ní aláraẹni fún ohunkóhun tí a bá ṣe lórúkọ ìgbékalẹ̀ náà.
Àwọn onípìn-ín-ìdókòwò náà sì tún máa ń jẹ̀gbádùn àtijẹ̀bi
onígbèdéke.
Àpẹẹrẹ kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke taráàlú ni Zenith
Bank Plc, Guinness Nig Plc.,
First Bank Plc., Dunlop Nig. Plc., UTC Nig. Plc. àti Texaco Nig. Plc.
*Advantages
of public limited liability company # Àwọn àǹfààní kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke taráàlú*
(1) Legal
entity # Ìgbékalẹ̀ abẹ́ òfin: Kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdéke taráàlú ní bíbẹ
lábẹ́ òfin. Ó ní ìláraẹni gedegbe yàtọ̀ sí àwọn olùni. Torínáà, ó
lè peni lẹ́jọ́ tàbí kí á pè é lẹ́jọ́ lórúkọ ara rẹ̀.
(2) Perpetual
existence # Bíbẹ títí: Ìtẹ̀síwájú
wà nínú kọ́ńpìnnì owó-ìdókòwò àjọdá. Ikú tàbí ìkúrò
onípìn-ín-ìdókòwò kan kò lè mú òpin bá òwò náà.
(3) Limited
liability # Àtijẹ̀bi onígbèdéke: Àtijẹ̀bi
rẹ̀ ní gbèdéke lórí iye tí a dókòwò gẹ́gẹ́ bí ojúowó sínú òwò
náà; kò sí ìlapa lórí àwọn dúkìá aláraẹni.
(4) Large
capital # Ojúowó gọbọi: Ó lágbára
láti kó ojúowó tító jọ nípa títa àwọn ìpín-ìdókòwò tàbí ẹ̀rí-ìjẹnígbèsè
(debentures) fún àwọn
aráàlu.
(5) Transferability
of shares # Àtiṣeétàtaré
ìpín-ìdókòwò: Àwọn ìpín-ìdókòwò ṣe í tàtaré láì nípa lórí
ìmúṣiṣẹ́ òwò náà.
(6) Loan
facilities # Àwọn ìrọ̀rùn ẹ̀yáwó: Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀
báńkì yàn láàyò láti máa fún àwọn kọ́ńpìnnǹ àtijẹ̀bi onígbèdéke taráàlú ní ẹ̀yáwó ju àwọn
ìgbékalẹ̀ òwò yòókù nítorí pé kò sí bóyá ìkùnà láti sanwó
padà.
(7) Economies
of large-scale
production # Ìṣọ́wóná ìgbéjáde olóṣùwọ̀n
ńlá: Kọ́ńpìnnì àtijẹ̀bi onígbèdeke taráàlú ní ojúowó tó pọ̀ tó
láti gbèrú, léyìí tí yóò yọrí sí ìgbéjáde yan̄turu níti àwọn
ire. Nípa báyìí, ìṣọ́wóná yóò wà nínú ìgbéjáde.
(8) Democracy
in management # Ìjọba-àwaarawa nínú
ìdarí: Láti yan ìgbìmọ̀ àwọn apàṣẹ, àwọn onípìn-ín-ìdókòwò ní ẹ̀tọ́
láti dìbò fúnni tàbí kí á dìbò fún wọn ní ìpàdé alákòópọ̀ ọlọ́dọọdún.
(9) Owners are
separated from management. # A ya àwọn
olùni sọ́tọ̀ kúrò lára ìdarí.: Àwọn onípìn-ín-ìdókòwò ni a kà
sí olùni kọ́ńpìnnì nígbàtí ìdarí wà lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ àwọn apàṣẹ.
(10)
Employees can become co-owners. # Àwọn òṣìṣẹ lè di alájọni.: Àwọn òṣìṣẹ́ lè di
alájọni òwò náà nípa ríra àwọn ìpín-ìdókòwò ní kọ́ńpìnnì
náà.
(11)
Recruitment of experts: Gbígba àwọn ọ̀jìnmì síṣẹ́: Kọ́ńpìnnì owó-ìdókòwò àjọdá máa
ń fa àwọn ènìyàn onímímọọ́ṣe àti alákọ̀ọ́mọ̀ mọ́ra láti ṣiṣẹ́ fún
un.
(12)
Research programmes # Àwọn ètò ìwádìí: Ní kọ́ńpìnnì owó-ìdókòwò, àǹfààní
púpọ̀ síi máa ń wà láti gùn lé àwọn ètò ìwádìí.
*Disadvantages of public limited liability
company # Àwọn àìláǹfààní kọ́ńpìnnì
àtijẹ̀bi onígbèdéke taráàlú*
(1) Lack of
privacy # Àìsí ìdákọ́ńkọ́: Kò sí
ìdákọ́ńkọ́ nítorí pé kọ́ńpìnnì náà ní láti ṣe ìtẹ̀jáde àwọn
àsùwọn àwòfín ọlọ́dọọdún rẹ̀ fún àwọn aráàlú.
(2) Conflict
of interest # Ìkọlura ìfẹ́-ọkàn: Ìṣeéṣe
wà fún ìkọlura ìfẹ́-ọkàn láàárín àwọn onípìn-ín-ìdókòwò, àwọn
apàṣẹ àti àwọn òṣìṣẹ́, léyìí tó lè lapa lórí ìjáfáfá àwọn
ìmúṣiṣẹ́ òwò náà.
(3) Slow
decision making # Ìfalẹ̀ ṣíṣe ìpinnu: Ṣiṣe
ìpinnu máa ń falẹ̀ nítorí ìfọ̀rọ̀lọ̀ àti ìjíròrò rẹpẹtẹ tó máa ń
wáyé nínú ètò-onípòjipò ìdarí.
(4) Separation
of owners from control # Ìyàsọ́tọ̀
àwọn olùni kúrò lára ìkójàánu: Àwọn olùni òwò náà (àwọn
onípìn-ín-ìdókòwò) kò lẹ́nu púpọ̀ tàbí rárá nínú ìṣètò òwò
náà, nígbà tó jẹ́ pé àwọn tó wà nídìí ìṣètò tí wọn kì í ṣe
olùni lè má fi taratara ṣiṣẹ́ náà.
(5) Hard to
establish # Ó ṣòro láti gbékalẹ̀: Àwọn
ìrìn-àjò àti ọ̀fíntótó tó wà nínú ìforúkọsílẹ̀ ṣòro, ó sì
díjú gidigidi.
(6) Payment of
large corporate tax # Sísan owó-orí ti kọ́ńpìnnì
gọbọi: A máa ń di àjàgà owó-orí tó wúwo lé wọn lórí, léyìí tó
máa ń jẹyọ látara èrè tí wọ́n kéde.
(7) Lack of
flexibility # Àìsí ìṣeétẹ̀: Kìkì òwò
tí ó wà nínú abala èròńgbà ti àwòránti ẹgbẹ́ ni kọ́ńpìnnì náà
lè ṣe. Kò lè dáwọ́le oríṣi òwò mìíràn.
(8) Decrease
in personal interest # Àdínkù ìfẹ́-ọkàn
aláraẹni: Irú ìfẹ́-ọkàn tí a máa ń fihàn nínú irú kọ́ńpìnnì yìí
sábà máa ń kéré tí a bá fi wé ti ìjólùni ẹlẹ́nìkan níbi tí
ìtara àti ìfẹ́-ọkàn ti ga gidigidi.
(9) Large
capital requirement # Ìnílò ojúowó gọbọi:
Ojúowó tí a nílò láti bẹ̀rẹ̀ àti láti mú kọ́ńpìnnì owó-ìdókòwò
àjọdá ṣiṣẹ́ ló sábà máa ń tóbi gidi.
*~Hakeem O. Adeniyan, 15/1/2022*
+2347034251583
Comments
Post a Comment