SOLE PROPRIETORSHIP # ÌJÓLÙNI ẸLẸ́NÌKAN
SOLE PROPRIETORSHIP # ÌJÓLÙNI ẸLẸ́NÌKAN
Oríkì:
Ìjólùni ẹlẹ́nìkan ni a le kì gẹ́gẹ́ bíi ìrí àdáwọ́lé òwọ̀ kan èyí
tí a ni, tí a fún ní owónàá, tí a sì darí lọ́wọ́ ẹnìkan ṣoṣo pẹ̀lú
àfojúsùn alákọ̀ọ́kọ́ láti mú èrè tóbi jùlọ. Ìjólùni ẹlẹ́nikan,
èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí òwò ẹlẹ́nìkan ṣoṣo, ni oríṣi ìgbékalẹ̀ òẁ
pípẹ́ jùlọ àti awọ́pọ̀ jùlọ.
A lè rí àpẹẹrẹ ìjólùni ẹlẹ́nikan
lọ́dọ̀ àwọn tẹ̀wétẹ̀wé, aránṣọ, atóríṣe, àti àwọn olórin.
*Characteristics Of Sole Proprietorship # Àwọn Àbùdá
Ìjólùni Ẹlẹ́nìkan*
1. Ownership # Níni: Ẹnìkan
ṣoṣo ló ni àdáwọ́lé òwò náà.
2. Objective # Èròńgbà:
Èròńgbà gbòógì òwò ẹlẹ́nìkan ṣoṣo ni láti jèrè.
3. Source of capital # Orísun
ojúowó: Olùni ló máa ń pèsè ojúowó láti bẹ̀rẹ̀ òwò náà àti
láti mu un ṣiṣẹ́.
4. Liability # Àtijẹ̀bi:
Olùni ẹlẹ́nìkan ní àtijẹbi aláìnígbèdéke.
5. Legal entity # Ìgbékalẹ̀
lábẹ́ òfin: Ìjólùni ẹlẹ́nìkan kì í ṣe ìgbekalẹ̀ lábẹ́ òfin nítorí
pé a kò lè ya olùni s̀́tọ̀ kúrò lára òwò rẹ̀ lábẹ́ òfin.
6. Management # Ìdarí:
Olùni ẹlẹ́nìkan fúnra rẹ̀ ló máa ń kójàánu, tó sì ń darí òwò
náà.
7. Lifespan # Gúngùn ẹ̀mí:
Gungun ẹ̀mi òwò gbára lé olùni. Àdáwọ́lé náà lè kógbáwọlé
nígbàkúùgbà.
*Source of Capital of a Sole Proprietorship # Orísun Ojúowó
fún Ìjólùni ẹlẹ́nìkan*
1. Personal savings # Àwọn àfipamọ́ aláraẹni
2. Loan from friends # Ẹ̀yáwó láti ọ̀dọ̀ àwọn
ọ̀rẹ́
3. Trade credit # Ìgbàwìn ọjà
4. Loan and overdraft from banks # Ẹ̀yáwó
àti àsanlé láti báńkì
5. Grants or loans from government # Ìfuǹni tàbí ẹ̀yáwó
láti ọ̀dọ̀ ìjọba
*Advantages Of Sole Proprietorship # Àwọn Àǹfààní
Ìjólùni Ẹlẹ́nìkan*
1.
It involves small
capital. # Ó nílò ojuowó kékere.
2.
It is easy to
establish. # Ó rọrùn láti dá sílẹ̀.
3.
Decisions can be
taken quickly. # Àwọn ìpinnu ṣeéṣe kíákíá
4.
It is easy to
manage. # Ó rọrùn láti darí.
5.
It requires small
operation. # Ó nílò ìmúṣiṣẹ́ kékere.
6.
All profits belong
to the owner. # Gbogbo èrè jẹ́ ti olùni.
7.
Sole proprietorship
can thrive in all business environments. # Ìjólùni ẹlẹ́nìkan ṣe
í lọ́yè ní onírúurú àyíká òwò.
8.
There is privacy in
conducting business affairs. # Ídákọ́ńkọ́ wà nínú ìmúrìn ọ̀rọ̀ òwọ̀ náà.
9.
There is a close
relationship between owner and employee. # Ìbáṣepọ̀ pẹ́kípẹ́kí
wà láàárín olùni àti òṣìṣẹ́ rẹ̀.
10.
There is a close
relationship between owner and customers. # Ìbáṣepọ̀ pẹ́kípẹ́kí
wà láàárin olùni àti àwọn oníbàárà rẹ̀.
11.
The sole proprietor
enjoys personal rewards because he has personal interest in the business. # Olùni ẹlẹ́nìkan
máa ń gbádùn àwọn ẹ̀san aláraẹni nítorí pé ó ní ìfẹ́ aláraẹni sí
òwọ̀ náà.
12.
There is effective
planning. # Àlàkalẹ̀ jíjáfáfá máa ń wà.
*Disadvantages Of Sole Proprietorship # Àwọn
Àìláǹfààní Ìjólùni Ẹlẹ́nìkan*
1. Problem of
continuity # Ìṣòro ìtẹ̀síwájú: Tí ikú olùni bá ṣẹlẹ̀, òwò náà lè
kú pẹ̀lú rẹ̀, àgàgà tó bá jẹ́ pé kò sí ajogún tí yóò gbaṣẹ́ lọ́wọ́
rẹ̀.
2. Inadequate capital # Àìtó ojúowó
3. The sole proprietor bears all risks alone. # Olùni ẹlẹ́nìkan
ló máa ń dánìkan forí la àwọn ewu.
4. Sole proprietorship has unlimited liability. # Ijólùni ẹlẹ́nìkan
ní àtijẹbi aláìnígbèdéke: Bí ìkùnà òwò náà bá ṣẹlẹ̀, àwọn
ohun-ìní àti dúkìá olùni ẹlẹ́nìkan ni yóò di títà láti sanwó fún
àwsn ayánilówó rẹ̀.
5. It is not a separate legal entity. # Kì í ṣe ìgbékalẹ̀
abẹ́ òfin tó dádúró: Lábẹ́ òfin, kò sí ìyàtọ̀ láàárín olùni ẹlẹ́nìkan
àti òwò náà fúnra rẹ̀. Òwò náà kò lè peni lẹ́jọ́ tàbí kí á pè
é lẹ́jọ́ lábẹ́ ẹ̀tọ́ ara rẹ̀.
6. He lacks specialization. # Kò ní ìlákànṣe:
Olùni fuǹra rẹ̀ máa ń wà nínú gbogbo abala òwò náà. Ó máa ń ṣiṣẹ́
kára; ó sì lè má gba ìsinmi àjọni, kì í sì í sábà sinmi. Lọ́pọ̀
ìgbà, tí ó bá ṣàìwá, òwò náà lè tì fún ìgbà díẹ̀.
7. There is limitation in expansion. # Gbèdéke wà fún ìgbèrú. Ìjólùni ẹlẹ́nìkan máa ń jìyà àtigbèrú látàrí àìtó ojúowó.
Comments
Post a Comment